Ọlawale Ajao, Ibadan
Ẹgbẹ awọn ọdọ Yoruba, iyẹn Yoruba Youth Socio-Cultural Association (YYSA), ti sọ pe o yẹ ki awọn aṣaaju Yoruba pẹlu awọn agbẹjọro ajijagbara ilẹ Yorùbá tẹpẹlẹ mọ igbesẹ lati dena bi ijọba orileede Benin ṣe n gbero lati fi Oloye Sunday Adeyẹmọ (Sunday Igboho) sọko pada sorileede Naijiria.
Ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Ọgbẹni Habib Ọlalekan Hammed, fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, O ni ohun ti ko bojumu ni bi ijọba ilẹ Naijiria ṣe n ṣe Igboho bii ẹni to fẹẹ ditẹ gbajọba.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ohun ti Sunday Igboho kọkọ gba lero ni lati gbeja awọn ẹya Yoruba lọwọ awọn apaayan to gba ilẹ baba wọn mọ wọn lọwọ.
“Wọn tan Igboho wọ ijijangbara fun idasilẹ ilẹ Oodua ni. Ohun to waa jẹ ki ijọba apapọ foju si i lara gẹgẹ bii ọta ijọba ni bo ṣe kọti ikun si ikilọ ti wọn fun un pe ko rọra maa sọrọ.
Ṣugbọn sibẹsibẹ ero ọkan Sunday Igboho daa, nitori ki i ṣe apo ara rẹ lo n ja fun.”
Ẹgbẹ naa waa rọ awọn agba Yoruba lati sa gbogbo agbara wọn ni gbogbo ọna lati yọ ajijagbara fun iran Yoruba naa kuro ninu igbekun ijọba Benin ati orileede yii.