Ẹgbẹ okunkun lawọn eleyii n ṣe n’Ikorodu, kọmiṣanna ọlọpaa lo mu wọn

Faith Adebọla, Eko

 

Ọwọ ọlọpa ti tẹ marun-un lara awọn gende to n ṣe ẹgbẹ okunkun niluu Ikorodu. Alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lọwọ ba wọn, wọn lawọn ọmọ yii wa lara awọn to n da omi alaafia ilu naa ru, ti wọn n ko awọn araalu laya soke.

Orukọ wọn ni Babatunde Tanimọwo, ẹni ọdun mọkanlelogoji, Kabiru Atanda, ẹni ọgbọn ọdun, Ibrahim Abubakri, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Gbọlahan Ọladimeji, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ẹni to ṣikarun-un,  tọjọ-ori ẹ si kere ju lọ ni Wasiu Rafiu, ẹni ọdun mọkandinlogun.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni borukọ Ikorodu ati agbegbe rẹ ṣe n ro gbọnmọgbọnmọ ninu iroyin lasiko yii, to si jẹ pe iro naa ki i ṣe iro rere, iro iwa janduku, ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, iwa ọdaran ati itajẹsilẹ, lo mu koun funra oun ko awọn ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ sodi lọ sagbegbe ọhun.

Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi to jẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko sọ f’ALAROYE ninu atẹjade to fi ṣọwọ lori iṣẹlẹ ọhun sọ̣ pe ninu awọn ile pako to wa laduugbo Agric ni wọn ti kẹẹfin awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun yii, ti wọn fi ko wọn.

Wọn ba awọn nnkan ija bii ada, aake, ọbẹ aṣooro, ẹgba (koboko), ninu awọn ile pako tawọn afurasi naa n gbe. Wọn ti wo awọn ile ọhun danu, wọn lawọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ti sọ ọpọ lara awọn ile naa di ibuba wọn, wọn tun palẹ awọn okuta ati igi ti wọn lawọn kan gbe di oju ọna agbegbe naa, titi kan awọn ṣọọbu ati kanta tawọn ọlọja kan fi di titi to yẹ ki mọto gba kọja.

Bi Adejọbi ṣe wi, awọn afurasi tọwọ ba yii ti jẹwọ pe ẹlẹgbẹ okunkun lawọn, kọmiṣanna si ti ni ki wọn fi wọn ṣọwọ si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, ki wọn le ran awọn agbofinro lọwọ ninu iwadii wọn, ki wọn too taari wọn siwaju adajọ laipẹ.

Odumosu tun ni lori ọrọ iwa ọdaran lagbegbe Ikorodu yii, bina o ba tan laṣọ, ẹjẹ o ni i tan leeekanna loun maa fi ọrọ naa ṣe.

Leave a Reply