Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ti ke si Gomina Adegboyega Oyetọla pe ko tete da mọto Jeep aadọrun-un ti awọn oṣiṣẹ rẹ ti ko lọ pada.
Ninu atẹjade kan ti Alakooso eto iroyin ẹgbẹ naa, Bamiji Ọladele, fi sita lo ti ṣalaye pe awọn ni akọsilẹ iye awọn oniruuru mọto nla nla ti awọn abẹṣinkawọ gomina ti pin mọ ara wọn lọwọ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ẹgbẹ PDP ti bẹrẹ si i kọ iwe ẹsun lẹkunrẹrẹ si awọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorileede yii, iyẹn, EFCC, ICPC atawọn mi -in lati ṣewadii awọn ti ijọba Oyetọla pin awọn ọkọ ọhun fun.
Ọladele sọ siwaju pe, “A ni ẹri aridaju nipa mọto mẹẹẹdogun to wa lakata iyawo gomina, mọto ogun (20) to wa lọdọ ọmọ gomina, a mọ nipa mọto nla nla bii ọgbọn ti awọn lọgaa lọgaa marun-un kan pin mọ ara wọn lọwọ.
“A ti ni akọsilẹ gbogbo awọn ọkọ yii pẹlu nọmba idanimọ wọn, a mọ nọmba ẹnijini wọn, a si mọ ipo ti ọkọọkan wọn wa ko too di pe wọn pin wọn mọra wọn lọwọ. A n ke si gbogbo awọn ti wọn gba mọto yii lati da wọn pada ko too di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii”
Nigba to n sọrọ lori ẹsun yii, Oludamọran fun gomina lori ọrọ oṣelu, Sunday Akere, sọ pe ki ẹgbẹ oṣelu PDP duro de asiko tiwọn pẹlu idaniloju pe ko si bojuboju kankan ninu gbogbo nnkan tijọba Oyetọla ṣe.
O ni Gomina Oyetọla ni eeku ida aṣẹ ti awọn araalu fun un lọwọ lati tukọ ipinlẹ Ọṣun di oru ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, gbogbo nnkan to ba si ṣe ni yoo jiyin.
Akere sọ siwaju pe ki ẹgbẹ PDP dẹkun ṣiṣe bii ọmọ oju-o-rọla-ri, ki wọn fi akọsilẹ ti wọn ba ni lori mọto ti wọn ba ro pe o sọnu sọwọ digba ti wọn yoo gba eeku ida, dipo ki wọn maa mu eto oṣelu gbona janjan.