Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹka tipinlẹ Kwara, ti yan Alaaji Babatunde Mohammed, gẹgẹ bii alaga tuntun ti yoo maa tukọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara, ni Saraki ba ni dandan agbara gbọdọ pada sọwọ PDP, lọdun 2023.
Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni awọn ẹgbẹ oṣelu to gbajumọ ju lorileede Naijiria APC ati PDP seto yiya awọn alaga ipinlẹ jake-jado ilẹ yii, eyi lo mu ki ẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara yan Alaaji Babatunde Mohammed, gẹgẹ bii alaga ti wọn si yan Umar Mohammed gẹgẹ bii agbakeji alaga.
Nigba ti olori awọn aṣofin agba tẹlẹ nilẹ wa, Sẹnetọ Bukọla Saraki, n sọrọ nibi ipade naa, o ni aaya ti bẹ silẹ, o ti bẹ sare, gbogbo ohun to ba gba ni awọn yoo fun un ẹgbẹ oṣelu PDP gbọdọ gbakoso iṣejọba pada lọdun 2023. O tẹsiwaju pe apẹẹrẹ ti han bayii pe ẹgbẹ naa yoo jawe olubori ni Kwara tori pe wọn fimọ sọkan, wọn o pin ara wọn yẹlẹyẹlẹ bi awọn ẹgbẹ kan ti wọn dara wọn si meji, o ni fun idi eyi, ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo jawe olubori nibi eto idibo to n bọ ni Kwara lọdun 2023.
Saraki waa sọ fun awọn oloye tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan ki wọn lọọ san sokoto wọn ko le, ki wọn si bẹrẹ ipolongo lati ile sile, ilu si ilu, ki wọn ma duro de pe o digba ti ajọ eleto idibo ba gbe atẹ jade ki wọn too bẹrẹ iṣẹ wọn.
Alaga wọn tuntun, Alaaji Babatunde, sọ pe ni orukọ oun ati oloye ẹgbẹ to ku, awọn dupẹ lọwọ ẹgbẹ ti wọn fi ọkan tan awọn, ti wọn si yan wọn sipo, o ni awọn ko si ni ja ẹgbẹ kulẹ, o tẹsiwaju pe gẹgẹ bii ọrọ ti Bukọla Saraki sọ, awọn yoo bẹrẹ iṣẹ ti oun yoo sa ipa oun ti ẹgbẹ naa yoo fi gbakoso ijọba ipinlẹ Kwara pada.