Ẹgbẹrun marun-un pere ni mo ti ri gba latigba ti mo ti n ba wọn lọ soko ole – Ahmed

Stephen Ajagbe, Ilorin

Afurasi ẹni ọdun marundinlọgbọn kan, Mọshood Ahmed, tọwọ ajọ NSCDC nipinlẹ Kwara tẹ fẹsun jiji ọkada gbe ti ni ẹgbẹrun marun-un pere loun ti i ri gba latigba toun ti n ba awọn ẹgbẹ oun lọ soko ole.

Ahmed, lasiko tawọn oniroyin n fọrọ wa a lẹnu wo ni olu ileeṣẹ ajọ naa to wa niluu Ilọrin, ṣalaye pe oun ki i ba wọn ji ọkada o, ṣugbọn oun loun maa n gbe wọn lọ si orita ti wọn ti n ja ọkada gba.

O ni igba mẹta ọtọọtọ loun ti gbe wọn lọ, igba akọkọ ti iṣẹ dahun, oun ri ẹgbẹrun marun-un gba, ṣugbọn ẹlẹẹkẹta toun maa lọ lọwọ palaba oun ṣẹgi.

Ọkunrin naa to ni ile Agọ, lagbegbe Pakata, niluu Ilọrin, loun n gbe loun kabaamọ pe oun ba awọn ẹgbẹ oun lọ soko ole.

O ni awọn ki i pa awọn ọlọkada tawọn ba gba ọkada lọwọ wọn, awọn kan maa ja wọn ju silẹ, tawọn si maa gbe ọkada wọn lọ.

Ahmed ni agbegbe Ode Alausa lawọn ti maa n saaba pade tawọn ba lọọ jale, awọn agbegbe Oojere, Mandate ati Adangba lawọn ti maa n ṣiṣẹ.

Alukoro ajọ NSCDC, Babawale Zaid Afọlabi, sọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karundinlọgbọn, lọwọ tẹ afurasi naa lagbegbe Adangba, niluu Ilọrin, lasiko toun pẹlu ẹgbẹ rẹ n lọ oko ole.

Afọlabi ni Ahmed pẹlu awọn meji mi-in ti wọn ti na papa bora bayii ti di ogboju ole ninu jiji ọkada gbe, paapaa ju lọ lọwọ alẹ.

O ni Ahmed funra rẹ jẹwọ pe aarin aago mejila alẹ si aago kan oru lawọn maa jade lọọ ṣiṣẹ naa.

O ni awọn ti gba aṣẹ ilẹ-ẹjọ lati fi afurasi naa sahaamọ titi di igba tawọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ to n yan iṣẹ lodi yoo fi pada sẹnu iṣẹ.

Leave a Reply