Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori tiyẹn ka a mọ pẹlu ẹ, iyawo ile kan ti ran awọn agbanipa si ẹgbọn ọkọ ẹ to n jẹ Moshood Orolade, o loun ko fẹ ki baba naa tu aṣiri iṣẹlẹ naa sita faye.
Bo tilẹ jẹ pe obinrin yii ṣi wa nibi to ti n jaye ori ẹ, sibẹ, ọwọ ti tẹ ọdaju eeyan to ran ẹni ẹlẹni lọ sọrun apapandodo, Success Samuel lo n jẹ.
Ki i ṣe pe ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46) yii, pẹlu awọn afurasi ọdaran ẹgbẹ ẹ pa Ọgbẹni Orolade nikan, wọn ti kọkọ ja oun atawọn ara ile ẹ lole owo, ẹrọ ibanisọrọ atawọn dukia wọn ki wọn too yinbọn pa baba naa danu.
Lara awọn ti wọn ja lole pẹlu Oloogbe Orolade lọmọbinrin ẹ to n jẹ Dasọla Orolade ati ọmọ ẹ ọkunrin to n jẹ Asimiyu Orolade.
Ni ọgbọnjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lalukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ ṣafihan Samuel pẹlu awọn afurasi ọdaran mi-in lorukọ CP Adebọwale Williams ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ naa.
Oṣifẹṣọ fidi ẹ mulẹ pe miliọnu mẹrin ataabọ Naira (₦4.5m) lobinrin naa ṣeleri lati fun un to ba ba a gbẹmi ẹgbọn ọkọ rẹ ko too di pe ọwọ awọn ọlọpaa to n tọpinin iṣẹlẹ ọdaran lawujọ tẹ ọkunrin afurasi apaayan naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii.
O ni, “ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lawọn adigunjale jalẹkun wọnu ile idile Orolade laduugbo Alakia, n’Ibadan, pẹlu ibọn, ada atawọn nnkan ija oloro mi-in, ti wọn si ja wọn lole dukia wọn.
“O ṣe ni laaanu pe awọn eeyan yii pa Ọgbẹni Moshood Orolade to jẹ lori idile yẹn, wọn si sa lọ lẹyin ti wọn huwa ika yii tan.
“Ni kete ti ẹka to n mojuto iwa ọdaran nileeṣẹ wa gbọ nipa iṣẹlẹ yẹn ni wọn ko awọn ọlọpaa lọ sibẹ lati wa awọn ọdaran yẹn ri.
Nigbẹyin gbẹyin, ọwọ papa tẹ ọga awọn afurasi ọdaran yẹn to n jẹ Success Samuel, nibi to sa pamọ si.
Ibọn ilewọ oyinbo kan to jẹ oloju meji, ọta ibọn mẹjọ, ọmọ-odo kan pẹlu apola igi kan ti wọn lo fun iṣẹ buruku yẹn lawọn ọlọpaa to mu Samuel ka mọ ọn lọwọ. Oun funra rẹ si ti jẹwọ pe oun loun pa Oloogbe Orolade loootọ”.
Samuel jẹwọ fawọn oniroyin pẹlu alaye pe ọrẹ oun kan to n jẹ Dele lọ bẹ oun lati gbẹmi baba onibaba.
O ṣalaye pe, “Dele lo waa ba mi lọjọ kan, o ni iya kan gbe iṣẹ ẹmi baba kan fun oun, ọun n wa ẹni to maa ba a pa a nitori aṣiri oun kan wa lọwọ baba yẹn ti oun ko fẹ ko tu sita nitori nnkan to le le oun kuro nile ọkọ oun ni bi aṣiri yẹn ba tu sita.
Dele gan-an lobinrin yẹn bẹ lati ba oun pa baba yẹn ki Dele too sọ fun emi”.
Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii ni Samuel ṣi wa lahaamọ awọn agbofinro ti wọn n ṣewadii awọn ọran to da.
Ni kete ti iwadii ọhun ba ti pari ni CP Williams yoo gbe e lọ sile-ẹjọ gẹgẹ bi SP Ọṣifẹṣọ ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn n’Ibadan.