Ẹjẹ eeyan lawọn eleyii rọ sinu kẹẹgi ti wọn ba lọwọ wọn

Adewale Adeoye

Bọrọ tawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna n sọ ba jẹ ootọ, ọsẹ yii ni wọn maa foju awọn afurasi ọdaran ikọ ẹlẹni mẹsan-an kan ti wọn mu fun iwa ọdaran bale-ẹjọ.  Ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn n pe ni ‘Neo Black Movement’ (NBM) ni wọn n pe ara wọn, oniruuru iṣẹ laabi lo si kun ọwọ wọn fọfọ ko too di pe awọn ọlọpaa fọwọ ofin mu wọn laipẹ yii.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn jẹ ikọ afeeyan ṣetutu-ọla, ti wọn maa n ba awọn to nilo ẹya ara wa wọn, ati pe wọn ba kẹẹgi nla kan lọwọ wọn ti wọn rọ ẹjẹ eeyan sinu rẹ.

Awọn afurasi ọdaran ọhun ni: Samson Ezekiel, ẹni ọdun mejilelọgbọn, Samuel Francis, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Usman Nura, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, Gabriel Sheba, ẹni ọdun mẹtalelogun, Haruna Sa’id, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, Bala Lukman, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Jabir Rilwan, ẹni ọdun mẹtadinlogoji.

ALAROYE gbọ pe itẹkuu kan to wa lagbegbe Dutse, ni Wọọdu Abba, to wa lojuna marosẹ Zaria si Kaduna, lọwọ awọn ọlọpaa agbegbe naa ti tẹ wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, A.S.P Mansur Hussain, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn araalu kan to mọ nipa iṣe ti ko bofin mu tawọn afurasi ọdaran ọhun n ṣe laarin ilu ni wọn waa fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe Saye Low-cost, to sun mọ ibi ti itẹku naa wa leti, tawọn si tete lọọ fọwọ ofin mu wọn.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe: ‘’Lẹyin tawọn ọlọpaa fọwọ ofin mu meje lara awọn ọdaran ọhun tan, a yẹ inu mọto jiipu kan ti nọmba rẹ jẹ RSH 712 CW wo daadaa, a ba awọn ẹru ofin nibẹ, lara awọn ohun ta a ba nibẹ ni ibọn oloju meji kan, ọbẹ aṣooro meji, ọpọ ọta ibọn, igba nla kan ati kẹẹgi nla kan ti wọn rọ ẹjẹ eeyan sinu rẹ to si kun fọfọ.

Iwadii ta a ṣe nipa awọn ọdaran ọhun fi han gbangba pe ọmọ ẹgbẹ tuntun wa lara awọn ta a mu lọjọ naa nitori pe, wọn ṣẹṣẹ ṣe ibura fawọn kan ninu wọn ni.

Ọdọ wa ni wọn wa tawọn ọdaran ọhun tun fi jẹwọ pe ẹjẹ baba agbalagba kan tawọn pa lawọn gbe sinu kẹẹgi ọhun ati pe loju-ẹsẹ lawọn ti sọ oku onitọhun nu sagbegbe Jaji, nijọba ibilẹ Igabi, nipinlẹ Kaduna, yii kan naa.

Wọn tiẹ tun sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn kan lo ko gbogbo ẹya ara to ṣe pataki lara oku baba tawọn pa naa lọ fun lilo.

Lẹyin ti wọn jẹwọ tan lawọn ọlọpaa tun lọọ fọwọ ofin mu awọn meji to ku lara ikọ wọn ni otẹẹli igbalode kan ti wọn n pe ni ‘ABU Congo Conference’ to wa lojuna marosẹ Jos, awọn tọwọ tun ba ni Ọgbẹni Austin Ifinju, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Aliyu Ali Yahaya ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Alukoro ni laipẹ yii lawọn maa too foju gbogbo wọn pata bale-ẹjọ ki wọn le fimu kata ofin niwaju adajọ.

Leave a Reply