Ọwọ tẹ ayederu ọmọ ogun oju omi to n lu awọn eeyan ni jibiti l’Ekoo

Adewale Adeoye

Ayederu ọmọ ogun oju omi kan,  Muhammad Tunde, ti wọn ti gbaṣẹ lọwọ rẹ lati ọdun 2000, nitori iwa palapala to hu, ṣugbọn to ṣi n lọ kaakiri igberiko, paapaa ju lọ, nipinlẹ Eko, lati maa lu awọn araalu ni jibiti.

ALAROYE gbọ pe o ti pẹ ti Tunde ti maa n gbowo lọwọ awọn araalu ti wọn ba nilo eeyan lati ba wọn da sẹria fawọn to ba ṣẹ wọn. Lẹyin to ba gba ẹgbẹrun lọna ogun Naira tan lọwọ awọn to nilo iranlọwọ rẹ ni yoo lọọ ba wọn ko awọn janduku wa pe ki wọn waa ba onitọhun lu ẹni to ṣẹ wọn, o si ti jingiri ninu iṣẹ laabi ọhun, ṣugbọn laipẹ yii ni ọwọ palaba rẹ segi, tawọn agbofinro si fi kele ofin gbe e.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe oṣiṣẹ otẹẹli kan ni Tunde lọọ ko janduku ba lẹyin to ti gba ẹgbẹrun lọna ogun Naira owo iṣẹ lọwọ ẹni tawọn alaṣẹ otẹẹli ọhun sọ pe ko ma mu siga ninu ọgba wọn mọ.

Ẹnu lilu ti wọn n lu ọkunrin naa lawọn alaṣẹ otẹẹli ọhun fi ranṣẹ pe awọn ọlọpaa agbegbe naa pr ki wọn waa fọwọ ofin mu Tunude atawọn janduku to ko wa. Ọdọ awọn ọlọpaa ni aṣiri ọmọkunrin naa ti tu pe ayederu ọmọ ogun oju omi ti wọn ti le danu lẹnu iṣẹ lati ọdun 2000 ni Tunde, ṣugbọn to maa n lọ kaakiri ipinlẹ Eko, to si n pe ara rẹ ni ojulowo ọmọ ogun oju omi ilẹ wa.

Alukoro ni awọn maa too foju rẹ bale-ẹjọ, ko le fimu kata ofin.

Leave a Reply