Eleyii ga o, wọn yinbọn pa ọlọpaa marun-un lẹnu iṣẹ 

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ebonyi, ṣi n wa awọn agbebọn kan ti wọn yinbọn pa ọlọpaa marun-un lẹnu iṣẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun  yii, lagbegbe Abakaliki, nipinlẹ naa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago marun-un aarọ kutukutu ọjọ yii lawọn ọlọpaa marun-un ọhun wa lẹnu iṣẹ lẹgbẹẹ biriiji kan ti wọn n pe ni Ebiya, lojuna marosẹ Hilltop, nijọba ibilẹ Abakaliki, nipinlẹ Ebonyi. Lojiji lawọn agbebọn ọhun ti ko sẹni to mọ ibi ti wọn ti n bọ pade awọn ọlọpaa ọhun. Ero ọkan wọn ni pe awọn agbofinro ọhun maa di wọn lọwọ lati kọja, bo tilẹ jẹ pe awọn yẹn ko tiwọn ro rara. Niṣe ni wọn ṣina ibọn fawọn ọlọpaa ọhun, ti wọn si pa marun-un danu laarin wọn, nigba tawọn yooku sa wọgbẹ.

Yatọ sawọn ọlọpaa tawọn agbebọn ọhun pa danu, awọn aṣẹwo meji kan ti wọn n pada lọ sile wọn naa pade iku ojiji, nitori pe ṣe ni ọta ibọn lọọ ta ba wọn nibi ti wọn duro si lẹgbẹẹ titi, ti wọn si ku loju-ẹsẹ.

Bẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii oṣu mẹta sẹyin ni awọn agbebọn kan pa ọlọpaa kan sagbegbe naa.

Leave a Reply