Ọlọpaa gba ẹgunjẹ lọwọ adigunjale, ni wọn ba tu u silẹ

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Mature, tile-ẹjọ Magisireeti kan to wa lagbegbe Morningside, lorileede Zimbabwe, ni wọn foju ọlọpaa mẹta kan, Ọgbẹni Albert Machona, ẹni ọdun mejilelogoji,  Charles Musiiwa, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati Ọgbẹni Tanyaradazwa Mhondiwa, ẹni ọgbọn ọdun ba. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ṣe apapin pẹlu adigunjale kan ti wọn mu laipẹ yii, wọn gbowo lọwọ rẹ, wọn si tu u silẹ pe ko maa lọ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ ku ogun iṣẹju lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ni awọn eeyan kan pe teṣan ọlọpaa pe ki wọn waa fọwọ ofin mu adigunjale kan,  Nyasha Foster, to maa n figba gbogbo da alaafia adugbo naa laamu. Wọn ni Foster lọọ digun ja ẹnikan lole, o si ji ẹgbẹrun lọna aadọta owo ilẹ okeere. Eyi lo mu ki awọn agbofinro lọ sibẹ, ti wọn si fọwọ ofin mu Foster, nibi tawọn araalu de e mọ. Lẹyin ti wọn mu un de teṣan wọn ni wọn beere ọrọ lọwọ rẹ, to si ṣalaye gbogbo b’ọrọ ọhun ṣe jẹ fun wọn. Ṣugbọn awọn agbofinro yii lẹdi apo pẹlu ọdaran ọhun, wọn jọ pin owo to ji gbe si meji, wọn ko o sapo, bẹẹ ni wọn ju Foster silẹ pe ko maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia.

Ko pẹ ti wọn ju Foster silẹ ni wọn lọọ ba ọgbẹni ti ọmọkunrin yii ja lole nileewosan to ti n gbatọju lọwọ, nitori ti Foster ṣe e leṣe lasiko ti wọn jọ n wọya ija. Ẹgbẹrun lọna mẹrindinlọgbọn Dọla pere ni wọn ko fun un, wọn ni iye ti awọn ri gba pada lọwọ ọdaran ọhun niyẹn.

Ọrọ ọhun ko tẹ ẹni to lowo lọrun, lo ba pe awọn to jẹ ọga awọn ọlọpaa ọhun, ni wọn ba bẹrẹ iwadii lakọtun. Lasiko naa ni aṣiri tu pe ṣe ni awọn ọlọpaa ọhun jọ ṣe apapin pẹlu adigunjale naa. Eyi lo mu ki wọn foju awọn ọlọpaa mẹta ọhun bale-ẹjọ lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Wọn ti fọwọ ofin mu Foster bayii, ti ọdaran ọhun si ti ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, o ni oun ṣetan lati sọ bọrọ ọhun ṣe jẹ fawọn agbofinro. Adajọ ile-ẹjọ ọhun ni ki wọn lọọ ju awọn ọlọpaa ọhun sahaamọ titi digba ti igbẹjọ maa waye lọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Leave a Reply