Idajọ iku lo yẹ ki wọn maa fun awọn ajinigbe-Rẹmi Tinubu

Oluṣẹyẹ Iyiade

Obinrin akọkọ l’orilẹ-ede Naijiria, Abilekọ Olurẹmi Tinubu, ni ẹjọ iku lo yẹ ki wọn maa da fun gbogbo awọn ọdaran ti wọn ba ti jẹbi ẹsun to ba ti ni i ṣe pẹlu ijinigbe.

Iyawo Aarẹ sọrọ yii nigba to n fi imọlara rẹ han lori bi awọn agbebọn ṣe ya bo ileewe alakọọbẹrẹ kan nipinlẹ Kaduna laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu yii, ti wọn si ji awọn akẹkọọ to to bii ọrinlelugba (280) pẹlu awọn olukọ wọn ko lọ.

Rẹmi Tinubu ni igbagbọ oun ni pe ẹnikẹni to ba ti n lọwọ ninu jiji awọn ọmọ keekeeke gbe gbọdọ jẹ alaaarẹ, ọdaju ati ojo eniyan. O ni bawo lẹni to gbadun tabi nilaari kan ṣe le wo sunsun, ko si lọọ ka awọn ọmọ keekeeke mọ yara ikẹkọọ wọn lati ji wọn gbe lọ.

Gẹgẹ bii ẹni to ti fi igba kan ri jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, Iyawo Aarẹ ni asiko ti to fun awọn aṣofin Naijiria ki wọn tete ṣofin ti yoo maa fi iya nla jẹ gbogbo ọdaran to ba ti jẹbi ẹsun ijinigbe, nitori awọn agba bọ, wọn ni: ‘ma fi oko mi ṣ’ọna, ọjọ kan naa leeyan n pinnu rẹ’.

 

Leave a Reply