Eemọ! Ọbọ ni ọkunrin yii pa to fi n kawọ pọnyin rojọ

Monisọla Saka

Ọrọ buruku toun tẹrin, ni iṣẹlẹ kan to waye niluu Awka, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Anambra, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun yii, lasiko tawọn ọdọ ilu atawọn igbimọ ilu fi panpẹ ofin gbe ọkunrin kan, ti wọn si pa a laṣẹ lati maa wi tẹnu ẹ, lori nnkan to gbe mi, to fi le pa iru ọbọ to rẹwa bẹẹ.

Gẹgẹ bii aṣa ati iṣẹdalẹ ilu Awka, wọn ni ohun ọwọ ni wọn ka ọbọ si ni gbogbo agbegbe naa, nitori bẹẹ ni o ṣe jẹ eewọ lati pa a, tabi jẹ ẹ.

Wọn ni ko jẹ tuntun lati maa ri ọbọ laarin igboro gbogbo ilu to wa labẹ Awka, koda wọn a maa fo wọnu agbala awọn eeyan, ti wọn ko si gbọdọ ṣe ohunkohun fun wọn.

Niṣe ni wọn da ọkunrin tọjọ ori rẹ yoo ti sun mọ aadọta, ṣugbọn ti ko darukọ ara ẹ ati ilu to ti wa lapa ilẹ Ibo nibẹ jokoo lati ṣalaye bọrọ ṣe jẹ to fi pa ọbọ naa, ki wọn le mọ iru idajọ to tọ si i.

Ọkunrin to n sọrọ naa lede Ibo ni oun ko ṣadeede pa ọbọ ti wọn gbe oku ẹ ti oun ọhun, o ni ẹranko igbo mi-in loun dẹ takute fun lati le r’oun se sinu isaasun oun, amọ to jẹ pe ọbọ yii lo lọọ ko si takute naa.

Nigba ti wọn beere igba to ti n gbe ninu ilu naa lati le mọ boya ko mọ ọn leewọ ni, o ni lati ọdun 2000, iyẹn ọdun mẹrinlelogun sẹyin bayii.

Bẹẹ loun mọ pe ofin ilu naa ni, awọn eeyan ilu Awka ko si ni i gba ki wọn pa ọbọ, depo pe eeyan maa jẹ ẹ.

Ofin yii lo ni oun ti n pa mọ lati ọdun toun ti n gbe niluu naa, ki i si i ṣe didun inu oun ni lati pa ẹranko ti ko ṣẹ oun ọhun.

Nigba to n bẹbẹ fun aanu lẹyin to mọ pe oun ti lu ofin ilu wọn, ọkunrin yii ni, “Mo mọ pe mo ti ṣe nnkan ti ko daa, amọ mo bẹ yin ni, ẹ jọọ, ẹ ma pa mi, ṣugbọn ẹ le wọ mi lọ sibikibi to ba wu yin”.

Awọn ọmọ oniluu ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo gba ipẹ rẹ, wọn ṣeleri pe awọn yoo da ẹmi rẹ si, bẹẹ ni ilu yoo tete gbe igbesẹ lati mọ bi wọn yoo ṣe ṣetutu fawọn alalẹ, lati dena ajalu buruku to le tẹyin ẹ jade.

Oniruuru ariwisi lawọn eeyan sọ si iṣẹlẹ yii lori ayelujara, nigba tawọn kan ri i bi nnkan radarada ti ko yẹ ko maa waye niru akoko ti oju ti la yii mọ, awọn mi-in, paapaa awọn ti wọn ti apa ibẹ wa sọ pe bayii la n ṣe nilẹ wa, eewọ ni nibomi-in.

Obinrin kan lo ṣe ẹkunrẹrẹ alaye lori idi to fi ri bẹẹ, o ni idaluu niṣelu. O ni idi ti wọn ṣe mu ọbọ ni pataki niluu Awka ni pe wọn ti ṣe awọn eeyan naa loore ri laye atijọ. Awọn ọbọ yii lo ni wọn maa n ta awọn eeyan ilu naa lolobo ti ogun abi wahala kan ba n wọlu bọ, nitori bẹẹ lo ṣe deewọ lati pa a tabi jẹ ẹ.

Leave a Reply