Ilẹ mọ ba awọn ajinigbe meji yii, akolo ọlọpaa ni wọn wa bayii

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ti mu awọn ọdaran meji kan, Ahmed Muhammad, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, to n gbe nijọba ibilẹ Song, ati Muhammad Haruna, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, to n gbe lagbegbe Jambutu, nijọba ibilẹ Yola North,  ti wọn yan iṣẹ ijinigbe laayo. O pẹ tawọn ọlọpaa ti n wa awọn ọdaran meji naa pẹlu bi wọn ṣe n ji araalu gbe, ti wọn aa si gbowo itusilẹ lọwọ awọn ẹbi ẹni ti wọn ba ji gbe ko too di pe wọn aa tu onitọhun silẹ.

Iṣẹlẹ ijinigbe kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣe gbẹyin yii leyii ti wọn ji Ọgbẹni Saddam Ahmadu, to n gbe lagbegbe Belel, nijọba ibilẹ Maiha, ati Buba Adamu, to n gbe lagbegbe Shani, nijọba ibilẹ Shani, lo sọ wọn di ọdaran tawọn ọlọpaa n wa ka.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lọwọ ọlọpaa tẹ wọn pẹlu iranlọwọ awọn ọdẹ adugbo, lẹyin ti wọn ti gba miliọnu marun-un din diẹ Naira lọwọ ẹbi awọn ti wọn ji gbe.

Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ naa, C.P Dankombo Morris, to ṣafihan awọn ọdaran ọhun fawọn oniroyin gboṣuba nla fun awọn ọdẹ adugbo naa atawọn ọlọpaa ti wọn jọ ṣiṣẹ papọ lati fọwọ ofin gba wọn mu.

Lara awọn ohun ija oloro ti wọn ba lọwọ wọn ni ibọn ṣakabula meji, ọta ibọn atawọn oriṣiiriṣii nnkan ija oloro miiran.

Ọga ọlọpaa naa waa ṣeleri pe laipẹ yii lawọn maa foju wọn bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn.

Leave a Reply