Eleyii gbẹnu tan! Alaaji Mashood ki ọmọ bibi inu ẹ mọlẹ, o ṣe ‘kinni’ fun un ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Baale ile kan, Alaaji Mashood, to n gbe ni agbegbe Ọlọrunṣogo, Bodè-Sáadú, nijọba ibilẹ Móòrò, nipinlẹ Kwara, to fipa ba ọmọ rẹ sun ti balẹ sile-ẹjọ Upper Area, niluu ọhun bayii, nibi to ti n sọ ohun to mu un ti ko fi ri ẹlomi-in ba laṣepọ ju ọmọ to bi ninu ara ẹ lọ.

ALAROYE gbo pe Simbiat, lo wọ baba rẹ, Alaaji Mashood, lọ sile-ẹjọ lẹyin tawọn ọlọpaa lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ niluu Bodè-Sáadú, nipinlẹ Kwara, nigba ti aṣiri bo ṣe n fipa ba ọmọ rẹ ti ko ju ọmọọdun mẹwaa lọ sun tu sita.

Simbiat ni ki baba oun maa ba oun sun ni gbogbo igba yii ti di baraku fun un latigba ti iya ati baba oun ti kọ ara awọn silẹ. Ọmọbinrin yii ni oun nikan ni ọmọbinrin ti iya oun bi fun baba oun ki wọn too kọ ara wọn silẹ.

“Iyawo keji ti baba mi fẹ ti ka emi ati baba mi mọ ibi ta a ti n ṣere ifẹ, ṣugbọn ṣe ni iyawo naa fi mi ṣe yẹyẹ, to si n sọ pe oogun owo ni wọn n lo mi fun.”

Agbẹjọro olujẹjọ, Barisita Toyin Ọnaọlapọ, rọ ile-ẹjọ lati gba beeli onibaara rẹ.

Onidaajọ Abdul Yẹkeen, gbọ si i lẹnu, o si gba beeli olujẹjọ, bakan naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

 

Leave a Reply