Ile-ẹjọ ni ki alaga PDP Ekiti ti wọn feṣun idaluru kan maa lọ layọ ati alaafia

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ Majisreeti kan ni Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ti paṣẹ itusilẹ alaga ẹgbẹ PDP tẹlẹ nipinlẹnaa,  Ọgbẹni Rọpo Adesanya, atawọn mẹrin miiran lori ẹsun igbimọ-pọ lati da wahala silẹ ati idunkooko lati da omi alaafia ilu ru ti wọn fi kan wọn lakooko ifinijoye ni ijan-Ekiti.

Awọn yooku ti wọn jọ fẹsun kan ni ni Oloye James Dada, Jẹgẹdẹ Ebenezer, Mathew Fabamiṣe ati Jẹgẹdẹ James. Awọn ọdaran wọnyi ni wọn ko wa siwaju Onidaajọ A.O Adeọsun, lọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ti wọn si fẹsun igbimọ-pọ lati da omi alaafia ilu rukan wọn.

Agbefọba, Ọgbẹni Johnson Okunade, ṣalaye pe awọn ọdaran wọnyi, ti alaga ẹgbẹ PDP tẹlẹri nipinlẹ Ekiti yii ṣaaju wọn ṣe ẹsẹ naa lọjọ kọkanlelogun, oṣun Kẹrin, ọdun to kọja yii, ni nnkan bii aago meje alẹ ni ijan-Ekiti. O ni wọn da wahala silẹ lakooko ifinijoye ọga ṣọja kan niluu naa, wọn si tun dunkooko mọ ọn pe awọn maa gbẹmi rẹ.

Pọsikutọ yii sọ pe awọn ọdaran naa ni wọn ba Ajagun-fẹyinti Ọlajide Ijadare, fa wahala niluu naa, ti ọga ṣọja tẹlẹri yii si waa fọrọ naa to wọn leti lagọọ ọlọpaa to wa niluu naa.

Ẹsun wọnyi ni agbefọba juwe gẹgẹ bii ohun to lodi sofin iwa ọdaran ti wọn kọ nipinlẹ Ekiti lọdun 2021.

Onidaajọ Adeọṣun sọ pe ọlọpaa olupẹjọ naa kunna lati mun ẹri to daju wa siwaju ile-ẹjọ naa, ati lati ko awọn ọdaran naa pọ mọ ẹsun idaluru ti wọn fi kan wọn. Bakan naa lo tun ṣalaye pe ẹsun igbimọ-pọ ti wọn fi kan wọn ko lẹsẹ nilẹ.

Adajọ ni, “Nigba ti mo wo gbogbo ọrọ naa pẹlu sùúrù, mo ri i pe ọlọpaa olupẹjọ yii kunna lati mu ẹri to daju wa siwaju ile-ẹjọ yii.

“Nidii eyi, mo tu gbogbo awọn eeyan naa silẹ lori ẹsun kin-in-ni, ekeji ati ìkẹta ti wọn fi kan wọn”

 

Leave a Reply