Lai fakoko ṣofo, Obaseki yan Godwin rọpo igbakeji rẹ ti wọn yọ nipo

Faith Adebọla

Lẹyin wakati diẹ ti wọn kede iyọnipo Ọgbẹni Philip Shuaibu, ti i ṣe igbakeji gomina tẹlẹri nipinlẹ Edo, Gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki, ti kede iyansipo Onimọ-ẹrọ Godwin Ọmọbayọ, ẹni ọdun mejidinlogoji (38), lati rọpo Shuaibu, ti wọn si ti ṣebura wọle fun un nile ijọba ipinlẹ Edo lẹsẹkẹsẹ.

Ẹnjinnia Ọmọbayọ ti Ọbaseki kede rẹ gẹgẹ bii igbakeji gomina tuntun yii jẹ ọmọ bibi ijọba ibilẹ Akoko Edo. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 1986, ni wọn bi i.

University of Benin lo ti kawe gboye ninu imọ ẹrọ (Electronics Engineering), o si ni Masitasi ninu imọ nipa eto ilu, (Public Administration).

Tẹ o ba gbagbe, lati ọpọ oṣu sẹyin ni lọgbọlọgbọ ti n lọ labẹnu laarin Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ati igbakeji rẹ latari awọn aigbọra-ẹni-ye kan.

Ina ija naa tubọ gbilẹ nigba ti Igbakeji Gomina kede pe oun yoo dije-dupo gomina ninu eto idibo to n bọ loṣu Kọkanla, ọdun yii, amọ ọga rẹ kọ lati ṣatilẹyin fun un.

Latigba naa ni ẹkọ ko ti ṣoju mimu laarin wọn, bii ekute ati ologbo si ni wọn n ṣe titi dakooko ti wọn yọ ọ bii ẹni yọ jiga yii.

Owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lawọn aṣofin ipinlẹ Edo buwọ lu iyọnipo Shuaibu, latari abọ iwadii ti igbimọ ẹlẹni meje kan, eyi ti Adajọ-fẹyinti S. A. Omonua, jẹ alaga rẹ fi ṣọwọ sileegbimọ aṣofin naa lọjọ Furaidee to kọja.

Ninu abajade iwadii naa, wọn ni Philip Shuaibu kọ lati yọju sawọn igbimọ oluṣewadii ọhun, bẹẹ ni ko kọwe tabi fi aṣoju kankan ranṣẹ titi ti wọn fi pari ijokoo wọn, ti wọn si fi esi ṣọwọ sawọn aṣofin, eyi ti wọn gun le ti wọn fi yọ ọ nipo bii ẹni yọ jiga lọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin yii.

Leave a Reply