Emi ni mo kunju oṣuwọn ju lọ lati pese idari to maa tun nnkan ṣe daadaa ni Naijiria – Ọsinbajo

Faith Adebọla

“Olori to ni iriiri ni Naijiria nilo lasiko ti nnkan le koko yii. Ọdun meje ti mo ti lo nipo igbakeji aarẹ ti fun mi ni iriri lẹnu iṣejọba, emi ni mo kunju oṣuwọn ju lọ lati pese idari to maa tun nnkan ṣe daadaa.”
Ọrọ yii lo tẹnu Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, jade laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii, niluu Asaba, nipinlẹ Delta, lasiko abẹwo rẹ si aafin ọba alaye ilẹ Ibo kan, Asagba tilu Asaba, Ọjọgbọn Chike Edozien.
Ṣibaṣiba lẹsẹ awọn aṣoju ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), ti ipinlẹ Delta, pe sibi ipade ti aarẹ ba wọn ṣe laafin ọba ọhun, nibi to ti n parọwa si wọn ki wọn le dibo foun, ki wọn si kin oun lẹyin fun ti eto idibo abẹle ẹgbẹ naa ti wọn yoo fi yan ọmooye sipo aarẹ, ti yoo ṣoju APC ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023.
Ọṣinbajo ni: “Tẹ ẹ ba yan mi sipo aarẹ, gbogbo nnkan to ba gba ni ma a ṣe lati ri i daju pe Naijiria bọ si ipo amuyangan to jẹ kadara ẹ lati ipilẹṣẹ wa. Alayeluwa, iroyin ayọ ni mo mu waa ba yin laafin o, mo fẹẹ sọ fun yin nipa ifẹ ọkan mi lati jade dupo aarẹ orileede wa, mo si fẹ kẹẹ wure fun mi, mo nilo adura ati ibukun yin.”
Ọsinbajo ni ki i ṣe pe oun ṣadeede bẹ gija sita lati dupo aarẹ o, o ni oun ti kọkọ ba Ọlọrun sọrọ nipa ẹ, oun si nigbagbọ pe Ọlọrun wa lẹyin oun.
Nigba to n fesi si ọrọ Ọṣinbajo, ọba alaye ṣadura fun un pe Ọlọrun aa ti i lẹyin. Bakan naa lo ran an leti pe ijọba apapọ ko kọbiara si ẹbẹ awọn lati ṣedasilẹ fasiti kan siluu Asaba, ati pe ọpọ awọn ilu ati igberiko lagbegbe naa ni ina ẹlẹntiriiki n jẹ niya gidi.

Leave a Reply