Faith Adebọla
Pẹlu bi eto idibo sipo gomina ipinlẹ Anambra eyi to waye lopin ọsẹ to lọ lọhun-un ṣe lọ wọọrọwọ, ti wọn si ti kede pe Ọgbẹni Charlse Chukwuma Soludo ti ẹgbẹ oṣelu APGA lo jawe olubori, ọrọ naa ti bẹyin yọ lopin ọsẹ yii. Ondije ti ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnetọ Andy Uba, ti faake kọri pe ile-ẹjọ lo maa yanju ọrọ naa, o si da oun loju pe oun ni wọn maa bura fun sipo gomina laipẹ.
Uba sọrọ idaniloju yii niluu Awka, nipinlẹ Anambra, nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ sọrọ lọjọ Satide, lori abajade esi idibo ọhun, ati igbesẹ to kan, o ni eru ati ẹtan nla lo waye lasiko idibo, ajọmọ Gomina Williams Obiano tipinlẹ ọhun, ẹgbẹ oṣelu APGA ati ajọ eleto idibo INEC lo pe eru naa, o ni wọn gbimọ-pọ lati ṣojooro ni.
“Bawo ni wọn ṣe le sọ pe mi o wọle ni Wọọdu mi, lẹhinkule mi nibi. Wọọdu mi to jẹ pe alaga ẹgbẹ oṣelu APGA paapaa di ọmọ ẹgbẹ wa lọsẹ to ṣaaju idibo, ojooro nla ni, jibiti ni.
Ṣugbọn mi o minkan rara, mo nigbọkanle pe ẹgbẹ APC maa gba ẹtọ ẹ ati esi ibo to tọna bọ lati ile-ẹjọ, mo si gbagbọ pe emi ni wọn maa bura fun sipo gomina laipẹ.”
Sẹnetọ Uba ni oun ki i sa fogun, toun ba si ti bẹrẹ si i jagun lori nnkan kan, o digba ti oun ba ṣẹgun koun too jawọ, o ni bẹẹ lọrọ yii ri.
Bakan naa lo bẹnu atẹ lu awọn agbaagba kan lẹgbẹ oṣelu rẹ to fẹsun kan pe wọn gbẹyin bẹbọ jẹ lori eto idibo naa, o ni wọn dalẹ ẹgbẹ, wọn dalẹ ara wọn, ṣugbọn wọn ro pe oun ni wọn dalẹ rẹ ni. O ni kawọn ololufẹ oun ma bọkan jẹ rara, tori asiko perete ni ayọ awọn ti wọn ro pe awọn lawọn wọle yoo fi wa, o ni ẹgbẹ oṣelu APC lawọn eeyan n fẹ, ile-ẹjọ si maa tun gbogbo nnkan to wọ lasiko idibo naa ṣe.
O tun fẹsun kan ajọ INEC pe wọn mọ-ọn-mọ huwa ojooro ni pẹlu bawọn ẹrọ wọn kan ṣe dẹnu kọlẹ lasiko idibo naa, tawọn oṣiṣẹ wọn ko si de sibudo idibo, paapaa lagbegbe oun, o laago mẹta ni wọn de, aago mẹrin si ni wọn ṣiwọ pe eto ibo ti pari.