Emi o sa lọ o, mo wa nilẹ Benin lati ṣatilẹyin fun Sunday Igboho ni-Ọjọgbọn Akintoye

Faith Adebola

Olori Ilana Oodua, Ọjọgbọn Banji Akitoye, ti sọ pe irọ to jinna si ootọ ni pe oun sa kuro ni orileede Naijiria. Baba to ti figba kan jẹ olukọ lawọn ileewe giga yunifasiti ni Amẹrika yii sọ pe oun wa ni orileede Olominira Benin lati ṣe atilẹyin fun Sunday ni, bi wọn ba si ti fi ajijagbara ọmọ Yoruba naa silẹ loun n pada bọ nile.

Baba ṣalaye ọrọ yii ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin rẹ, Maxwell Adelẹyẹ, gbe jade lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

‘Loootọ ni mo wa ni ilẹ Olominira Benin, ṣugbọn ki i ṣe pe mo sa lọ, mo wa nibẹ lati mojuto gbogbo igbokegbodo awọn agbẹjọro ati gbogbo igbesẹ to ba yẹ lati ri i pe a gba Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Igboho kuro lahaamọ ni.’

Akintoye ni bo ṣe jẹ pe Igboho ko ṣẹ ẹṣẹ kankan loun naa ko ṣẹ ẹnikẹni, oun ko si ṣe lodi sofin Naijiria ti yoo fi di pe ẹnikan yoo maa halẹ mọ oun tabi mu oun.

‘Ominira Yoruba ni a n wa, ofin agbaye fara mọ ọn, ofin Naijiria paapaa ko lodi si ki a beere fun iru nnkan bayii. Ohun yoowu ti ijọba Buhari le maa gbero si mi, mo fẹẹ fi da yin loju pe mo n pada bọ ni Naijiria, nitori mi o ṣẹ si ofin kankan to le mu ki wọn maa wa mi kiri tabi halẹ mọ mi.

‘Gẹgẹ bii akọni ologun, mo ṣetan lati pada si orileede Naijiria bi ohun gbogbo lori ọrọ Sunday Igboho ba ti yanju.’ Bẹẹ ni Baba Akintoye sọ ninu apa kan ninu atẹjade naa.

Leave a Reply