Emi o sọ fẹnikan pe ẹya Igbo nipo aarẹ kan lọdun 2023 o – Ọbasanjọ

Gbenga Amos, Abeokuta

Olori orileede wa tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ ọrọ to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara pe oun ti fọwọ si i ki ẹya Igbo bọ sipo aarẹ lẹyin ti Muhammadu Buhari ba ti pari saa rẹ, lọdun 2023, bẹẹ loun o si ṣadehun pẹlu ẹnikẹni lati ṣatilẹyin fun ẹya Igbo lati de ipo ọhun.

Ọbasanjọ ni bo ba jẹ Ọgbẹni Mao Ohuabunwa, ọkan lara awọn to fẹẹ dupo aarẹ lọdun 2023, lo wa nidii ahesọ bẹẹ, ọna ti ko daa lo gbe ọrọ gba niyẹn, ki i ṣe ohun to tọ rara.

Ninu atẹjade ti Amugbalẹgbẹẹ fun Ọbasanjọ lori eto iroyin, Kẹhinde Akinyẹmi, fi lede lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹta yii, lorukọ ọga rẹ, o ni:

“O (Ohuabunwa) wa sibi loootọ lati ṣabẹwo si Oloye  Ọbasanjọ, wọn si gba a lalejo daadaa gẹgẹ bii ọmọluabi ati latari ayẹyẹ ọjọọbi ọdun karundinlaaadọrin to n ṣe lọwọ, bawo lo ṣe waa di pe o bẹrẹ si i sọ ohun ti baba ko sọ. Baba (Ọbasanjọ) o ki i ṣeru eeyan to n sọrọ bẹẹ, bo ba si jẹ ọna toun fẹẹ gbe ilepa ẹro rẹ nidii oṣelu gba niyẹn, ọna ti ko daa ni.

Atẹjade naa rọ awọn araalu lati ma maa yara gba gbogbo ọrọ gbọ, ki wọn si maa ṣewadii lati fidi ootọ mulẹ nigba gbogbo.

Leave a Reply