Emmanuel yii ma laya o, ọlọpaa lo fẹẹ yinbọn mọ n’llọrin ti wọn fi mu un

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Afurasi kan, Emmanuel Oluwafẹmi, ti ṣi iṣẹ ṣe bayii o. Ọlọpaa ti ko wọsọ lo fẹẹ yinbọn mọ ti wọn fi mu un. Ṣe oun ko kuku mọ pe agbofinro ni wọn, nitori wọn ko wọsọ iṣẹ. Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ kin-in-in, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lọwọ ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ẹka awọn to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, ‘Human Rights Section’ (CID), ẹka tipinlẹ Kwara, tẹ ẹ lasiko to fẹẹ yinbọn pa ọlọpaa kan to sọ fun un pe iwakuwa ọkọ lo n wa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Victor Ọlaiya, ṣalaye fawọn oniroyin niluu Ilọrin, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, pe ni ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni ASP Sunday Adamọlẹkun, to wa ni ẹka to n ja fun ẹtọ ọmọniyan mu gende-kunrin kan, Emmanuel Oluwafẹmi, to n gbe ni Alubarika Villa, lagbegbe Òkè-Oṣè, Ilọrin, nipinlẹ Kwara, wa si ileeṣẹ ọlọpaa, to si ṣalaye pe oun ati ASP Adepọju Taiwo, lawọn n dari lọọle ninu ọkọ Toyota Corolla, tawọn ti wọn si ri afurasi yii to n wakọ niwakuwa lagbegbe ikorita Gaa-Àkàbí, to si bẹrẹ si i bu awọn ọlọpaa mejeeji, nigba to ya lo mu ibọn ilewọ kekere kan jade, to si yin-in soke lẹẹmarun-un ko too di pe ibọn naa ko yin mọ.

O tẹsiwaju pe nigba ti ibọn ko yin mọ ni Emmanuel fere ge e, ko too di pe awọn araadugbo mu afurasi yii, ti wọn si fa a wa si agọ ọlọpaa.

Ọlaiya sọ pe nigba ti wọn tu ara afurasi yii, wọn ba ibọn ilewọ kekere kan, ibọn kan ti wọn n pe ni pump-action, to ni iwe rẹ ati iwe irinna, to fi mọ awọn oogun abẹnugọngọ.

O ni awọn ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ Emmanuel, nitori pe gbogbo akitiyan ọlọpaa ni lati ri i daju pe iwa ọdaran dohun igbagbe nipinlẹ Kwara.

Ọlaiya ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii lawọn yoo foju afurasi naa balẹ-ẹjọ.

Leave a Reply