Awọn eleyii ji kẹkẹ Maruwa tuntun mẹta gbe l’Ekoo, Ondo ni wọn ti mu wọn

Faith Adebọla

Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Eko, labẹ idari Kọmiṣanna ọlọpaa, CP Fayọade, ti tẹ gende mẹrin kan to jẹ jiji kẹkẹ Maruwa ni iṣẹ ti wọn yan laayo. Kẹkẹ mẹta ni wọn lọọ ji gbe nileeṣẹ kan ti wọn ti n ta awọn kẹkẹ naa, kọwọ palaba wọn too segi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fi ọrọ yii lede loju opo ayelujara rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ileeṣẹ kan ti wọn ti n to kẹkẹ Maruwa pọ, ti wọn si ti n ta a, eyi to fikalẹ si agbegbe Ọjọta, nipinlẹ Eko, lawọn afurasi ọdaran yii wọ, ti wọn si ji kẹkẹ mẹta gbe.

Hundeyin ni Akọwe ileeṣẹ onimaruwa ọhun lo mu ẹsun wa sileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti Ogudu, ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, pe awọn firi-nidii-ọkẹ, alọ-kolohun-kigbe ẹda kan ti palẹ kẹkẹ mẹta mọ nileeṣẹ awọn ni nnkan bii aago meje idaji ọjọ naa.

Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti fọn sode, ti wọn si bẹrẹ si i tọpasẹ kẹkẹ naa kiri. Nibi ti wọn ti n fimu finlẹ ni wọn ti ri awọn afurasi ọdaran ti wọn ko fẹẹ darukọ wọn lasiko yii mu.

Hundeyin ni, “Ilu Ondo, nipinlẹ Ondo, ni wọn ti mu afurasi ọdaran kin-in-ni, wọn tọpasẹ rẹ dọhun-un ni, wọn si ba kẹkẹ Maruwa tuntun ti wọn ji lọwọ rẹ, nigba tọwọ ba afurasi keji ni agbegbe Mile 12, l’Ekoo, pẹlu kẹkẹ kan. Ipinlẹ Ogun, niluu Idiroko, leti ẹnubode Naijiria ati ilẹ Olominira Benin, lọwọ ti ba ẹni kẹta ati ẹkẹrin wọn pẹlu kẹkẹ tuntun ti wọn ji ọhun.

O ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn, ati pe kete lẹyin iwadii, gbogbo wọn yoo lọọ kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.

Leave a Reply