Faith Adebọla
Eeyan mẹfa, ninu eyi ti ọmọọwọ kan wa, lo ti kile aye pe o digbooṣe, latari awọn ijamba ọkọ to waye lọna Ilaro, lagbegbe Yewa, ati loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, nipinlẹ Ogun, lopin ọsẹ yii.
Gẹgẹ bi Adari eto iroyin fun ajọ awọn ẹṣọ ojupopo apapọ, Federal Road Safety Commission ( FRSC), ẹka tipinlẹ Ogun, Abilekọ Florence Okpe, ṣe fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin ta a wa yii, o ni ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ owurọ ọjọ Satide naa, lọna marosẹ Eko s’Ibadan, lagbegbe Ogere, ni ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry kan ti nọmba rẹ jẹ LAGOS BDG526JC ti sare asapajude, o lere naa kọja sisọ debi t’ọkọ ọhun fi ya kuro lori titi ọlọda, to si takiti lai kọ lu ọkọ mi-in. Eeyan meje lo wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ ọhun, obinrin agbalagba mẹrin, ọkunrin agbalagba kan, ọmọdekunrin kan ati ọmọdebinrin kan.
Loju-ẹsẹ ni obinrin kan ati ọmọdebinrin aarin wọn ti ku patapata, nigba tawọn marun-un yooku fara pa yannayanna, ti wọn si sare gbe wọn digbadigba lọ sileewosan Idera Hospital, to wa ni Ṣagamu, ọsibitu naa ni wọn ko oku awọn meji to doloogbe si.
Bakan naa, ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to ṣaaju, iyẹn ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lagbegbe Ogere yii kan naa, lọna marosẹ Ijẹbu-Ode si Ọrẹ, ọkọ akẹru DAF ti nọmba rẹ jẹ AYE886ZQ ati ọkọ akẹru Volvo ti nọmba rẹ jẹ MUS 246 YH sẹri mọ ara wọn lori ere, oju-ẹsẹ leeyan meji ti doloogbe, bo tilẹ jẹ pe awọn marun-un ni wọn wa ninu ọkọ mejeeji ọhun.
O lawọn ti ko awọn to fara gbọgbẹ lọ sọsibitu ijọbato wa n’Ijẹbu Ode fun itọju pajawiri.
Iṣẹ aṣelaagun lawọn oṣiṣẹ Road Safety ṣe ki wọn too le ri oku awọn mejeeji naa yọ, tori niṣe ni wọn ha saarin awoku ọkọ to run jege naa. Amọ nigbẹyin, wọn yọ wọn, wọn si ko wọn lọọ mọṣuari ọsibitu Ijẹbu Ode. Ere asapajude lo ṣokunfa ijamba yii gẹgẹ bi wọn ṣe wi.
Lọjọ Furaidee yii kan naa, nitosi Iyana Idọgọ, lọna to lọ lati Ilaro si Owode, ọkọ ayọkẹlẹ Mitsubishi kan ti nọmba rẹ jẹ JJJ954JH, ati ọkọ akẹru to ni nọmba T12224LA sẹri mọ ara wọn. Eeyan meje lo wa ninu ọkọ mejeeji, obinrin mẹrin, ọkunrin mẹta, amọ lẹsẹkẹsẹ ni meji ninu wọn ti ku, awọn yooku si fara gbọgbẹ gidigidi. Wọn ti ko wọn lọ sọsibitu ijọba to wa niluu Ilaro, fun itọju pajawiri.
Ọga agba ajọ Road Safety nipinlẹ Ogun ti koro oju si bawọn awakọ ṣe maa n paaki ọkọ nla sẹgbẹẹ titi lai bikita, bẹẹ lo ṣekilọ lori ere asapajude awọn onimọto, o leyii lo saaba maa n ṣokunfa ijamba ọkọ to n da ẹmi awọn ero legbodo.