Ẹni to ba n bu mi n fi akoko ara ẹ ṣofo lasan ni – Biṣọọbu Oyedepo ṣalaye ọrọ

Awọn eeyan Aarẹ Muhammadu Buahri kan ti bẹrẹ si i bu olori ijọ Winnners, Biṣọọbu David Oyedepo, nitori ọrọ kan ti ojiṣẹ Ọlọrun naa sọ nibi iwaaasu rẹ lori redio, wọn ni ko sinmi, ko yee pariwo ẹnu. Ṣugbọn Oyedepo funra rẹ ti sọrọ, o ni bi eeyan kan ba n bu oun, o n fakoko ara ẹ ṣofo lasan ni, nitori oun ko gbọ eebu naa, bi oun si gbọ, oun ko ni i dahun, tori pe a-gbọ́-má-bi-wọ́n ẹda kan loun.

Ohun to ṣẹlẹ ni pe  ijọba ṣẹṣẹ gbe ofin kan jade, Buhari si ti fọwọ si i. Ofin ti eeyan fi le da ileeṣẹ, ẹgbẹ alaaanu, ile ijọsin bii ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi silẹ ni, tabi bii ẹgbẹ ọmọọlu, tabi ẹgbẹ awọn ọmọ ẹya kan naa bii Afẹnifẹre. KI i ṣe pe ko si ofin yii tẹlẹ, ijoba ṣe iyipada si i ni. Ayipada ti won ṣe ni pe bi ẹgbẹ, ṣọọṣị tabi ileeeṣẹ kan ba ṣe aṣemaṣe to bi ijọba ninu, ijọba lẹtọọ bayii lati gba ileeṣẹ naa lọwọ awọn to ni in. Bo si jẹ ṣọọsi ni, bo ti wu ko tobi to, ijọba le gba a lọwọ ẹni to ni ti yoo si di tiwọn, wọn yoo si sọ ẹni to ba ni in, tabi awọn eeyan ti wọn n ṣe e, si korofo. Labẹ ofin yii, bi iru ṣọọṣi Ridiimu, tabi ijọ Nasfat, tabi ẹgbẹ Afẹnifẹre, ba ṣe ohun kan to lodi sofin, tabi ti ko tẹ ijọba lọrun, ijọba le gba wọn lọwọ awọn to ni wọn, ti ẹgbẹ tabi ijọ naa yoo si di tijọba.

Ohun to dun Oyedepo niyi, o si ni ofin naa ki i ṣe ofin daadaa, pe ọna lati pa awọn araalu tabi ẹgbe to  n sọrọ ta ko ijọba Buahri yii lẹnu mọ ni won ṣe ṣe ofin naa, ati pe ofin to le ba nnkan jẹ lọjo iwaju ni. Oyedepo ni iru nnkan bayii, to ba ṣẹlẹ, bi ileeṣẹ tabi ẹgbẹ, tabi ijọ kan ba ṣe aṣemaṣe, ile-ẹjọ lo ye ki wọn gbe ọrọ naa lọ, gẹgẹ bo ṣe wa ninu ofin Naijiria tẹlẹ, ki iṣe ki ijọba kan jokoo si Abuja, ki wọn deede gba nnkan naa lọwọ awọn to ni in. O ni kin ni ijọba pa ofin ti a n lo tẹlẹ rẹ si, pe ki wọn tete yaa da a pada, o le da biliisi sile lọjọ iwaju.

Ko sọ ju bẹe lọ, ṣugbọn kia lawọn eeyan Buhari ti ki i mọlẹ, ẹni kan ninu wọn to jẹ oludamọran fun Aarẹ, Lauretta Onochie, si sọ pe bi Naijiria ko ba tẹ Oyedepo lọrun mọ, ko ko jade nibẹ, ko lọọ da orilẹ-ede tirẹ silẹ, nitori ki i ṣe dandan ni pe ko ba wa gbe. Awọn ọrọ ibinu bayii ni Oyedepo fesi si, to ni bẹni kan ba n bu oun, o n fi akoko ara rẹ ṣofo lasan ni.

3 thoughts on “Ẹni to ba n bu mi n fi akoko ara ẹ ṣofo lasan ni – Biṣọọbu Oyedepo ṣalaye ọrọ

  1. Ṣe ìjọba àwa ará wa ni a nṣe ni orile-ede Naijiria tàbí ìjọba ológun, gbogbo nkán ti wọn kò jẹ danwo ni orilẹ èdè ibòmíràn ní a nṣe ni orile-ede Naijiria

  2. Hmm ero teminiwipe wonfepa ile yoruba run nio. Se ile yoruba nikan ni nasfat wa . Sebi yoruba na loni egbe afenifere ti ijoba sowipe awon legbese le. Hmm . Yoruba ejekaronu wo. Ija n bo. Kannakanna ti n yo omo ega. Ejekafura. Kafi enu arawa so nkan taofe o. Atiwipe. Ile labo sinmin oko.abo oro lan sofun omoluwabi o. Iree o

Leave a Reply