Ẹniọla Ajao onitiata bu sẹkun gbaragada: Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ ṣaanu mi o

Monisọla Saka

Latari rogbodiyan ati akọlukọgba laarin awọn oṣere tiata, olorin atawọn ilu-mọ-ọn-ka, eyi to waye lẹyin ti wọn ṣafihan fiimu tuntun ti Ẹniọla Ajao ṣẹṣẹ ṣe, obinrin onitiata to ni fiimu Ajàkájù naa ti sọrọ.

Ninu ọrọ itọrọ aforiji ati ẹbẹ to gbe sori ayelujara, ni Ẹniọla ti tuuba lọwọ gbogbo awọn eeyan, awọn ẹlẹsin Musulumi, gbogbo obinrin pata ati ni paapaa ju lọ, awọn to peju-pesẹ sibi ayẹyẹ afihan fiimu rẹ, to fi mọ awọn oṣere ẹgbẹ ẹ ti wọn ti tori ọrọ naa gbena woju ara wọn.

Bo tilẹ jẹ pe Ẹniọla pada jẹwọ pe ọrọ aje loun fi ami-ẹyẹ to tọ si obinrin, ṣugbọn tawọn gbe fun Bobrisky ti iṣe ati imura rẹ jọ ti obinrin ṣe, o ni ẹru k’oun ma jẹ gbese, k’oun si le pa owo rọgunrọgun toun na lori fiimu naa nigba toun ko ri iranlọwọ lọdọ ẹnikẹni, lo fa nnkan t’oun ṣe.

O fi kun ọrọ rẹ pe oun ko gba a lero lati fi fiimu oun akọkọ ti yoo wọ sinnima da iyapa silẹ laarin awọn oṣere ẹgbẹ oun ati awọn ololufẹ oun. Oṣere yii ni oun gba lati gba gbogbo ẹbi yoowu ti wọn ba fẹẹ di ru awọn igbimọ onidaajọ ti wọn mu Bobrisky ati Fẹmi Adebayọ.

O ni oun ti ṣe wahala gan-an, owo to si le ni igba miliọnu Naira loun na lori fiimu yii. Nitori bẹẹ lo ṣe jẹ pe gbogbo ọna ti fiimu naa yoo fi ba ọja, ti yoo si jẹ atẹwọgba laarin ilu ati lọdọ awọn to maa n ṣedajọ lori musemuse fiimu kọọkan loun n wa.

Nitori ibẹru pe kawọn eeyan ma fi ti Bobrisky ti wọn gbe ami-ẹyẹ fun dẹyẹ si oun ati fiimu to ni wọn yoo bẹrẹ si i maa ṣafihan rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, ni Ẹniọla ṣe jade sita lati tọrọ aforiji awọn eeyan.

Ninu lẹta to fi sita ọhun lo ti ni, “Ẹyin eeyan mi pataki, pẹlu ọkan to wuwo, to si kun fun abamọ ati ironupiwada ni mo fi kọwe si yin lonii lori nnkan to ṣẹlẹ nibi afihan fiimu mi tuntun, Ajàkájù, to waye lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

“Mo n ba gbogbo yin sọrọ lonii, bẹẹ ni mo gba gbogbo ẹbi to tibẹ jade, ti mo si tun n bẹbẹ fun aforiji yin pẹlu abamọ lori rogbodiyan ati wahala ti eto to waye lasiko afihan fiimu Ajàkájù da silẹ.

“Lakọọkọ, mo fẹẹ bẹbẹ, bẹẹ ni mo fẹẹ tọrọ aforiji lọwọ awọn Musulumi, agaga ninu oṣu mimọ Ramadan yii. Mo mọ ipa ati riri asiko ta a wa yii, ki i si i ṣe erongba mi ni lati ṣẹ tabi da inu bi ẹnikẹni pẹlu gbogbo eto to waye nibi afihan fiimu mi.

Ẹ jọọ, ẹ foriji mi, ẹ gba ẹbẹ mi lori gbogbo wahala yoowu ti nnkan ti mo ṣe ti le da silẹ ninu oṣu mimọ yii.

“Si awọn obinrin wa laarin ilu, ẹ jọọ, ikunlẹ mi ree. Emi alara gẹgẹ bii obinrin, mo mọ pataki gbigbe ati ṣiṣe apọnle obinrin ẹgbẹ mi pẹlu iyi ati apọnle to ga.

Mo n fi da yin loju pe mi o figba kankan kọ iyan obinrin kere, mi o si ni i mọ-ọn-mọ hu iwa ti yoo mu adinku tabi tabuku ipa awọn obinrin lawujọ laelae.

“Bakan naa ni mo tun n fi asiko yii tọrọ aforiji lọwọ Fẹmi Adebayọ, iyawo wọn, Iya Aladukẹ ati Dayọ Amusa, nitori awọn abuku ati iyẹpẹrẹ loriṣiiriṣii to ba wọn latari ẹni ti wọn kede bii obinrin to mura ju nibi ayẹyẹ wa. Mo kabaamọ gbogbo awọn ọrọ eebu ati abuku ti wọn fi kan wọn, mo si gba ẹbi gbogbo nnkan ti eleyii ti le da silẹ.

“Si Bobrisky, mo tọrọ aforiji fun bi mo ṣe ko ẹ si yọọyọọ. Erongba wa lati fun ẹ ni ami-ẹyẹ ki i ṣe lati ba nnkan jẹ tabi da ija silẹ, amọ to jẹ ọna lati ṣe igbelarugẹ fun fiimu wa, ki o le baa rin jinna. Mo tọrọ aforiji fun inira ati ipalara ti gbogbo eyi ti le da silẹ fun ẹ.

“Lojuna ati ṣe atunṣe ati lati pa aṣiṣe mi rẹ, mo ti ṣetan lati fi ami-ẹyẹ obinrin ti imura rẹ dara ju nibi eto naa da Bọde Alao ati obinrin mi-in lọla, pẹlu ẹbun miliọnu kan Naira fun ẹni kọọkan wọn gẹgẹ bii ẹbẹ fun idariji, ati imọriri imura ati bi wọn ṣe wa sibi eto ọhun.

“Mo fẹ ka mọ pe koko erongba mi lori gbogbo ọrọ yii ni ọna lati gbe fiimu mi larugẹ, eyi ti yoo wọ awọn sinnima kaakiri lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Nigba to ṣee ṣe ki n ti ṣi ẹsẹ gbe lawọn asiko yii, mo fẹ kẹ ẹ mọ pe mi o ni ero ibi tabi eyi to le ko ipalara ba ni lọkan. Ẹ ma binu, mo tọrọ aforiji fun gbogbo inira ti nnkan ti mo ṣe yii ti le bí. Bẹẹ ni mo ṣi wa lẹnu ki n maa kẹkọọ kun ẹkọ ati idagbasoke lara iriri yii. Mo maa mọ riri idariji ati atilẹyin yin gidi gan-an ni”.

Tẹ o ba gbagbe, latigba ti wọn ti kede Idris Okunẹyẹ, ọkunrin ti iṣe, iwa ati imura ẹ jọ ti obinrin, to si maa n pera ẹ lobinrin, tawọn eeyan mọ si Bobrisky, gẹgẹ bii obinrin ti imura rẹ jọju ju nibi ayẹyẹ afihan fiimu Ajàkájù ti Ẹniọla ṣẹṣẹ ṣe, ni ija nla ti bẹ silẹ laarin awọn oṣere tiata.

Nigba tawọn kan ko fi bẹẹ pariwo lori bi ọrọ naa ko ṣe dun mọ wọn, Dayọ Amusa lo kọkọ sọ aidunnu rẹ lori ọrọ yii, Fẹmi Adebayọ ni iwo ọrọ naa si ṣẹ mọ lara.

Lori ede aiyede aarin Dayọ ati Fẹmi yii, ni Iya Aladukẹ, ti i ṣe iyawo Fẹmi Adebayọ ati Jigan baba ọja ti i ṣe onitiata bii tiẹ naa ti doju ija kọ Dayọ.

Oriṣiiriṣii orukọ ni wọn ti pe Fẹmi Adebayọ nitori bo ṣe kede Bobrisky. Awọn mi-in si bu u pe ko tilẹ wo o pe inu aawẹ loun wa to fi ṣe nnnkan to ta ko ẹsin ati eto awujọ ọhun.

Bakan naa ni ọrọ yii tun bi ija nla, to n fojoojumọ ran bii ina inu ọyẹ laarin gbajumọ olorin taka-sufee nni, Habeeb Okikiọla Ọmọlalọmi, tawọn eeyan n pe ni Portable Zaazu Zeh, ati Bobrisky ti wọn fun ni ami-ẹyẹ nibi eto naa.

Awọn alawada ori ayelujara, atawọn ololufẹ awọn gbajumọ ẹda wọnyi, ni wọn ti tori ọrọ yii doju ija kọra wọn. Eyi lo mu ki ọlọrọ funra ẹ, iyẹn Ẹniọla Ajao, jade sita waa bẹbẹ, lojuna ati le bomi pana aawọ naa.

 

Leave a Reply