Fijilante yii ti daran o, afurasi ti wọn fa le e lọwọ lo dana sun

Monisọla Saka

Ọgbẹni Adekunle Agunbiade, ti i ṣe ọkan lara awọn fijilante to n ṣọ adugbo kan lagbegbe Itirẹ, nipinlẹ Eko, ti wa ni teṣan ọlọpaa, nibi to ti n ṣẹju peupeu, lẹyin to dajọ lọwọ ara ẹ, to si ran afurasi ti wọn fa le e lọwọ lọrun apapandodo.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe sọ lati ẹnu SP Benjamin Hundeyin, ti i ṣe alukoro wọn, mọto kan ti wọn paaki si Opopona Shonde, Itirẹ, nipinlẹ Eko, ni wọn ni ole naa n ji nnkan tu lara ẹ lasiko ti ọwọ tẹ ẹ.

Hundeyin ni, “Ni nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni ẹni kan pe teṣan ọlọpaa Itirẹ nipe pajawiri, pe ole kan wọ adugbo awọn wa, o si ti fọwọ ba mọto oun.

“O ni lẹyin toun kegbajare, ọwọ ba ọkan lara awọn ole naa, awọn si fa a le Ọgbẹni Adekunle Agunbiade ti i ṣe ọkan lara awọn ọdẹ to n ṣọ adugbo naa lọwọ.

Ọkunrin to pe agọ ọlọpaa yii ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ f’oun nigba toun pada gbọ pe wọn ti dana sun ole tawọn fa le wọn lọwọ, dipo ki wọn fa a le ọlọpaa lọwọ”.

Alukooro ọlọpaa ni ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin fijilante to dana sun afurasi ole yii, awọn si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply