O ti dofin o, ẹwọn taara ni ẹni to ba ji ina ijọba lo n lọ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ileeṣẹ to n pin ina ijọba ni ẹkun Ibadan, Ibadan Electricity Distribution Company (IBEDC) Plc, ti sọ pe ọrọ jiji ina ijọba lo to ti di tọrọfọn-kale yii yoo rokun igbagbe laipẹ, nigba ti awọn kọlọransi yii ba n ri idajọ to wa nidii ẹ.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọga agba ileeṣẹ naa, Johnson Tinuoye, ṣe ṣalaye, iwa jiji ina ijọba lo ti di iwa ọdaran to wa ninu akọsilẹ ti wọn pe ni Electricity Act, lara ijiya rẹ si ni ẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara.

O ni laarin oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, si ọṣe keji, eeyan ẹẹdẹgbẹjọ o din diẹ, (1459), lọwọ tẹ lori ẹsun pe wọn n ji ina ijọba lo.

Latati idi eyi ni ajọ IBEDC ṣe pinnu lati ṣiṣẹ papọ pẹlu igbimọ amuṣẹya kan tijọba apapọ gbe kalẹ, iyẹn Federal Government Special Investigation and Prosecution Task Force on Electricity Offences (SIPTEO).

O ni ajọ yii pẹlu IBEDC ni wọn yoo jọ maa ṣiṣẹ papọ lati fi pampẹ ofin mu ẹnikẹni tabi ileeṣẹ ti ajere iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori, ti wọn yoo si maa foju wọn ba ile-ẹjọ.

Lara awọn iwa tawọn kọlọransi naa n hu, to si n pa ajọ IBEDC lara, gẹgẹ bi Tinuoye ṣe wi ni yiyọ ina kalẹ nidii mita, gbigbe ina gba ọna ẹyin wọnu ile, gbigbe ina kọ waya lalaalẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O ni ọkẹ aimọye miliọnu Naira ni ileeṣẹ naa n padanu lojoojumọ latari iwa ibajẹ ti opọ eeyan n hu ọhun, ti ko si jẹ ki awọn lanfaani lati ṣe ojuṣe awọn bo ti tọ fawọn araalu ti wọn jẹ olootọ.

Tinuoye sọ siwaju pe nipinlẹ Ọṣun nikan, eeyan meji lọwọ ti tẹ lori jiji ina ijọba lo, awọn mejeeji si ti foju bale-ẹjọ.

O ke si awọn araalu lati dẹkun iwa naa nitori igbimọ amuṣẹya ti yoo bẹrẹ si i lọ kaakiri bayii ko ni i gbọjẹgẹ rara, ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo si fimu danrin ofin.

Leave a Reply