Nitori bi ileeṣẹ IBEDC ṣe ja ina wọn, awọn oṣiṣẹ ileewosan UCH fẹẹ daṣẹ silẹ n’Ibadan

 Ọlawale Ajao, Ibadan

Afi ki gbogbo ẹni to ba ni alaisan to n gbatọju nileewosan ijọba apapọ, iyẹn University College Hospital (UCH), to wa niluu Ibadan, tete maa gbadura kun aawẹ to n lọ lọwọ bayii, pẹlu bi awọn oṣiṣẹ ileewosan naa ṣe fẹẹ bẹrẹ iyanṣẹlodi bayii.

Eyi ko ṣẹyin bi gbogbo ileewosan naa ṣe wa ninu ookun bayii, nitori ileeṣẹ to n pin ina ẹlentiriiki n’Ibadan ati agbegbe ẹ (IBEDC), ti ṣe ja ina wọn danu, wọn ni wọn jẹ gbese owo ti ti ko din ni miliọnu marundinlẹẹẹdẹgbẹta Naira (₦495m).

Nibi ipade ajumọṣe ti apapọ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ loniran-nran to wa nileeṣẹ ọhun ṣe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn (27-03-2024), lori papa iṣere to wa ninu ọgba ileewosan naa ni wọn ti kede igbesẹ yii.

Lara awọn ẹgbẹ to ni aṣoju ninu ipade ọhun ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ti wọn ki i ṣe olukọ (NASU); ẹgbẹ awọn nọọsi ati agbẹbi (NANNM); ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ eleto ilera (NUAHP), pẹlu ẹgbẹ awọn agbaagba oṣiṣẹ ileewosan naa ti wọn n pe ni SAUTHRIAN.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade ọhun, Adari egbẹ JAC, iyẹn ẹgbẹ to ko gbogbo awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ileewosan UCH pọ patapata, Ọgbẹni Oludayọ Ọlabimpe, fidi ẹ mulẹ pe ko ni i ṣee ṣe ki awọn maa ri itọju awọn alaisan atawọn iṣẹ mi-in ṣe daadaa nigba ti ko ba si ina ijọba.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni, ‘‘Lati ọjọ Tusidee, ọsẹ to kọja, ni wọn ti ge ina UCH danu, wọn la a jẹ gbese miliọnu marundinlẹẹẹdẹgbẹta Naira (₦495m), awọn ko si ni i da ina naa pada, afi ta a ba san eyi to jọju ninu owo ta a jẹ naa.

“A o le maa ba a lọ bayii, nitori iṣẹ yii ko ṣee ṣe lai si ina. Ohun to si fi mu ki iru eleyii ṣẹlẹ si UCH, a jẹ pe gbogbo Naijiria lọrọ yii kan niyẹn, nitori ileewosan ijọba apapọ ilẹ yii ni UCH jẹ”.

O waa rọ ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ iṣakoso Gomina Ṣeyi Makinde, lati dide iranlọwọ si ileewosan naa lati le doola ẹmi awọn ọmọ Naijiria ti wọn n gba itọju nibẹ.

Leave a Reply