Ọba Ẹlẹkọle ti Ikọle dawati laafin, ni gbogbo ara ilu ba n jaya

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ibẹru ati ipaya lo wa lọkan awọn eeyan ilu Ikọle-Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, nipinlẹ Ekiti, pẹlu bi Kabiyesi ilu naa, Ọba Adewumi Ajibade Fasiku, ṣe ṣa deede poora laafin, ti ko si si ẹnikankan to mọ ibi ti ori-ede yii wa.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ ilu yii, ni pataki ju lọ, awọn oloye, ẹlẹgbẹ-jẹgbẹ awọn ọdọ atawọn araalu miiran ni gbogbo wọn ti n kọminu pẹlu bi wọn ko ṣe mọ ibi kan pato ti ọba naa wa.
Lakooko abẹwo ti akọroyin wa ṣe siluu naa laipẹ yii, lara awọn ọmọ ilu ọhun ṣalaye fun wa pe awọn ko le sọ akoko kan pato ti ọba wọn ti fi ori oye silẹ, awọn miiran sọ pe o ti to ọdun meloo kan, nigba ti awọn miiran n sọ pe o ti fẹẹ to ọdun mẹta ti awọn ti foju kan Ọba Ajibade Fasiku ni gbangba ita.”

Eyi to buru ju ninu ọrọ naa ni pe Kabiyesi kọ lati ba ẹnikẹni sọrọ yala awọn oloye tabi awọn ọmọ ilu naa. Awọn kan sọ fun akọroyin wa pe awọn mọ daju pe ọba naa ko gbadun, ṣugbọn awọn ko mọ pato iru aisan to n yọ ori-ade yii lẹnu.

Oniṣowo kan niluu naa to ba akọroyin wa sọrọ, ṣugbọn to kọ lati darukọ ara rẹ sọ pe, “A gbọ pe Kabiyesi lọọ gba iwosan l’Oke-Okun lati bii ọdun mẹta, ti awọn kan si sọ pe yoo pada sile ko too di ipari oṣu to n bọ, eleyii ti yoo fi opin si ọdun mẹta to ti fi ilu silẹ lai dagbere fun ẹnikankan’’.

Awọn kan sọ fun ALAROYE pe bi ọba alaye yii ṣe ṣadeede fi ilu silẹ ki i ṣe oju lasan, eyi gan-an lo fa ibẹru ati ipaya niluu naa. ‘‘Bi Ẹlẹkọle ṣe ṣadeede filu silẹ ti fa ipinya laarin ilu naa, ni pataki ju lọ, laarin awọn oloye. Awọn oloye ko le ṣe ipade ti wọn maa n ṣe lọjọ mẹsan-mẹsan ni aafin pẹlu Kabiyesi mọ, nigba ti ko si ọba alaye yii nile, ti ko si dagbere fun wọn. Ni pataki ju lọ, awọn oro ati oriṣa ti wọn maa n ṣe niluu ko waye mọ.” Ọmọ ilu naa to jẹ olukọ nileewe girama kan lo sọ eyi.

Ni bayii, ẹgbẹ kan ti orukọ wọn njẹ “Save Ikọle Group” ti kọ lẹta si ijọba ipinlẹ Ekiti, lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ti wọn si fi aidunnu wọn han bi ọba ilu wọn ṣe ṣadeede fi ori ipo silẹ.

Ninu lẹta naa, wọn rawọ ẹbẹ si Gomina Biọdun Oyebanji pe ko ṣe ohun gbogbo lati ri i pe Kabiyesi pada siluu naa.

Leave a Reply