Gọngọ sọ nile-ẹjọ lasiko igbẹjọ ti awọn aafaa Ilọrin pe Saheed Shittu waye

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, nile-ẹjọ Upper Area, to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo tẹsiwaju lori ẹjọ ti awọn aafaa Ilọrin pe Saheed Shittu.

Saheed Shittu ni ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Ogo Ilọrin, iyẹn (Association of Proud Sons and Daughters of Ilọrin) pe lẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ ati titabuku awọn aṣaaju ẹṣin ati awọn eniyan pataki niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.

Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ ọhun ṣe gbe e kalẹ, awọn eeyan pataki ti Saheed Shittu tabuku ọhun ni, Sheikh Labeeb Adam Al ILory, Sheikh Sulaiman Faruq Onikijipa (Grand Mufti ilu Ilọrin), Sheikh Muhideen Salman (Imamu agba iluu Ọffa), Sheikh Amahullah Folorunshọ Faagba, Sheikh Adam Abdullah Al ILory, Sheikh Kamaldeen Al Adaby ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni ile-ẹjọ ti paṣẹ fun awọn ọlọpaa lati mu Saheed Shittu, ki wọn si wọ ọ wa si ile-ẹjọ nigba ti ko ti yọju fun ara rẹ

Bakan naa ni Saheed ko tun yọju si ile-ẹjọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ṣugbọn agbẹjọro rẹ yọju lati duro fun un.

Agbẹjọro Aafa Saheed Shittu, Oloye Abdulfatai Abdulsalam, pe akiyesi ile-ẹjọ si iwe atako to gbe wa sile-ẹjọ, nibi igbẹjọ to ti kọkọ waye ṣaaju.

Iwe atako naa n pe fun ki ile-ẹjọ wọgi le idajọ ranpẹ to ṣagbekalẹ lori pe ki ọlọpaa nawọ gan olujẹjọ naa nibikibi ti wọn ba ti ri i.

Ninu idahun rẹ, agbẹjọro ẹgbẹ Ogo Ilọrin, Ademọla Ajasa, sọ pe ki ile-ẹjọ fun awọn ni aaye diẹ lati fesi si iwe atako naa.

Lẹyin awuyewuye awọn mejeeji yii, Onidaajọ Sunday Adeniyi, sun igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, fun igbẹjọ lori iwe atako naa.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu agbẹjọro Saheed Shittu, Oloye Abdulfatai Abdulsalam, lẹyin igbẹjọ, o ni onibaara oun ni awọn idi pataki ti ko fi yọju si ile-ẹjọ, awọn si ti ṣalaye fun ile-ẹjọ.

Leave a Reply