Gomina Adeleke fẹẹ ṣatunṣe awọn ileewe ẹkọṣẹ ọwọ to wa l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina Ademọla Adeleke ti sọ pe gbogbo awọn ileewe ẹkọṣẹ ọwọ mẹsẹẹsan to wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun ni atunṣe to yoo ba laipẹ.

Lasiko to ṣabẹwo si ọga agba ileeṣẹ Innovation Hub, Ọgbẹni Meir Dagan, ẹni to jẹ akọṣẹmọṣẹ to n ṣe awọn iṣẹ naa ni gomina ti sọrọ idaniloju yii.

O ni, “A ko le pa iru iṣẹ bantabanta bẹẹ ti. A nilo awọn ileewe ẹkọṣẹ ọwọ lati le din wahala airiṣẹ ṣe to pọ kaakiri orileede yii bayii. Bawo ni gomina ti awọn araalu dibo yan yoo ṣe diju si oniruuru awọn iṣẹ akanṣe ti Arẹgbẹṣọla dawọ le ko too kuro lọfiisi. Ai ni imọlara ohun ti awọn araalu n la kọja ni.

‘’Ṣebi ijọba maa n tẹsiwaju ni. Ni ti temi atawọn abẹṣinkawọ mi, gbogbo awọn iṣẹ akanṣe ti a jogun ba la maa pari, bẹẹ la si maa bẹrẹ tiwa naa.

‘’Mo fẹẹ kede rẹ gbangba fun gbogbo aye pe a-gbe-n-de ti ba awọn ileewe ẹkọṣẹ ọwọ to wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun lati wakati yii lọ’’

Adeleke rọ ọga agba naa lati ran awọn oṣiṣẹ rẹ sipinlẹ Ọṣun lati ji iṣẹ naa dide lọtun. O ni ko ni i dun mọ ohun ninu ti ọpọlọpọ awọn irinṣẹ ti wọn tilẹkun mọ sibẹ ba bajẹ.

Nigba to n fun gomina labọ lẹyin to ṣayẹwo awọn ileewe ẹkọṣẹ ọwọ naa, Ọgbẹni Dagan sọ pe ileeṣẹ oun ti ṣetan lati tun iṣẹ akanṣe naa sọ bii ẹni sọgba.

O fi idunnu rẹ han si ipinnu Gomina Adeleke lori awọn ileewe ẹkọṣẹ ọwọ ti yoo pese iṣẹ fun ọpọlọpọ, ti yoo si tun mu ki ọrọ-aje rugọgọ kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

 

Leave a Reply