Ọlawale Ajao, Ibadan
Nnkan ko ṣenuure fun oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu All Pprogressives Congress (APC), Sẹnetọ Teslim Fọlarin, lagbo oṣelu pẹlu bi diẹ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun kan ṣe pada lẹyin ẹ, ti wọn si pinnu lati satilẹyin fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ninu idibo opin ọsẹ yii, ki ọkunrin naa le wọle idibo lati ṣe saa keji nileejọba.
Awọn eeyan ọhun, ti wọn fi mẹjọ din ni ọrinlelọọọdunrun (372,000) ni wọn jẹ ẹgbẹ alatilẹyin fun aarẹ ti araalu ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lẹkun Guusu orile-ede yii.
Nigba ti wọn n ṣabẹwo si ọfiisi Amofin Adebayọ Lawal ti i ṣe igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ẹgbẹ ọhun sọ pe nitori aṣeyọri nla ti ijọba Makinde ṣe lawọn ṣe pinnu lati ṣatilẹyin fun un ko le tẹsiwaju ninu iṣẹ rere naa ni saa keji.
Oludari ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Adebayọ Moronsọle ati
Ọgbẹni Emmanuel Adesanya, ti i ṣe olupolongo ibo fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ninu ẹgbẹ APC ni wọn pinnu lati ri i daju pe Gomina Makinde wọle idibo fun saa keji nile ijọba nitori pe o wa lara awọn gomina to ṣe daadaa ju lọ laarin ọdun 2019 sasiko yii.
Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ waa lu awọn ẹgbẹ naa lọgọ ẹnu fun ipinnu wọn lati gbaruku ti Gomina Makinde lati wọle ibo fun saa keji.
O waa ṣeleri pe ijọba Makinde yoo tubọ maa sa ipa wọn lati ri i pe idagbasoke ba ipinlẹ Ọyọ ju ti saa akọkọ lọ.