Ẹru inu oteẹli ti Bankọle ba de si lo maa n ji ko, ọwọ ti tẹ ẹ n’Ibadan

Faith Adebọla
Ọgbọnkọgbọn buruku kan lafurasi ọdaran ẹni ọdun mẹtalelogun pere yii, Mustapha Bankọle, maa n da to fi n ji awọn tẹlifiṣan ati dukia otẹẹli gbe n’Ibadan, ṣugbọn ni bayii, ọwọ palaba rẹ ti segi.
Agbegbe Bodija si Sango, niluu Ibadan, lọwọ ti tẹ afurasi ọdaran yii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin ta a wa yii, awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni wọn dọdẹ ẹ, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Adewale Oṣifẹsọ ṣe wi.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o mura bii eeyan gidi, o ṣe bii arinrin-ajo to fẹẹ gba yara mọju, lo ba lọ si otẹẹli nla kan nijọba ibilẹ Ariwa Ibadan, o ni ki wọn fun oun ni yara.
Ọgbọn ti jagunlabi yii da ni pe o sọ fawọn oṣiṣẹ otẹẹli naa pe yara to wa nitosi ẹnu ọna abajade ni ki wọn fun oun, tori oun ṣi n reti awọn alejo kan ti wọn n bọ lati irinajo, ati pe yara meji si mẹta loun maa nilo, wọn si ṣe bẹẹ fun un.
Lọganjọ oru tọwọ ti pa tẹsẹ ti pa, jagunlabi ko irinṣẹ to fi n jale jade, o bẹrẹ si i tu awọn tẹlifiṣan ati nnkan eelo abanaṣiṣẹ ti wọn fi ṣe awọn yara naa lọṣọọ, bo ṣe n tinu yara kan bọ si omi-in lo n yọ dukia wọn, o sọ oṣiṣẹ olugbalejo to wa nidii kanta abawọle otẹẹli naa, koloju si too ṣẹ ẹ, o ti ko awọn ẹru ole naa jade.
Nigba tawọn oṣiṣẹ yoo fi ṣabẹwo si yara naa, ki wọn le ṣe imọtoto wọn laaarọ ọjọ keji, gau ti gbọn igba, korofo ni wọn ba yara, ni wọn ba lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa to wa ni Bodija.
Nigba tọwọ ba a, Bankọle jẹwọ pe loootọ loun huwa ọhun, oun si ti n ṣe bẹẹ tipẹ. Wọn lo tun darukọ awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ, atawọn to n ba a ra ẹru ole to ba ji ko, pẹlu awọn onimọto ti wọn n ba a ko o.
Wọn ba tẹlifiṣan Samsung alẹmogiri tigbalode oni-inṣi mejilelọgbọn meji to ṣẹṣẹ ji tu loru mọju ọjọ naa, ati awọn dukia mi-in to jẹ ti otẹẹli naa.
Ṣa, wọn ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ yii, ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni afurasi naa ati awọn ẹru ole rẹ rẹ wa, wọn si ti n dọdẹ awọn onigbọwọ rẹ to darukọ.
Alukoro ọlọpaa lawọn maa wọ ọ lọ sile-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply