Esi ayẹwo ti wọn ṣe si oku Timothy Adegoke ti jade o

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iroyin to tẹ Alaroye lọwọ ti fidi rẹ mulẹ pe esi ayẹwo ti awọn dokita ṣe si oku akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, to ku sinu Otẹẹli Hilton, ti jade.

Gẹgẹ bi ẹnikan ti ko fẹ ka darukọ oun ṣe sọ, oni Ọjọruu, Wẹsidee, ni wọn fi esi ayẹwo naa ranṣẹ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ni Abuja.

A gbọ pe wọn tun mu ẹda esi ayẹwo naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Oṣogbo.

Ṣugbọn nigba ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, n sọrọ lori ẹ, o ni iwadii iṣẹlẹ naa ti kuro lọdọ awọn, olu ileeṣẹ ọlọpaa l’Abuja lo laṣẹ lati sọrọ lori ẹ bayii.

Amọ ṣa, ẹgbọn oloogbe, Gbade Adegoke ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i ranṣẹ pe awọn mọlẹbi, awọn ti gbọ pe esi ayẹwo naa ti wa nileeṣẹ ọlọpaa niluu Oṣogbo ati l’Abuja.

Gbade fi kun ọrọ rẹ pe awọn ko ti i mọ esi ayẹwo naa, ṣugbọn awọn mọ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo pe awọn lori ẹ laipẹ.

Ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni awọn akọṣẹmọṣẹ ṣe ayẹwo si oku Timothy ni Osun State University Teaching Hospital, Oṣogbo, odidi wakati mẹrin ataabọ ni wọn si lo lori ẹ.

Nipa ohun to wa ninu esi ayẹwo naa, ẹnikan to ti lanfaani si i sọ pe ayẹwo ọhun fi han pe inu inira nla ni Timothy wa to fi jade laye (Severe Trauma).

Leave a Reply