Ibọn meji ni wọn ba lọwọ Abdullahi l’Alaba, o ni ole loun fi n ja

Faith Adebọla, Eko

 Ẹni ọdun mọkanlelogun pere ni Abdullahi Zakari to loun n gbe agbegbe Ọjọọ, nipinlẹ Eko, ṣugbọn akolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọkunrin naa wa lasiko yii. Ibọn meji ti wọn ba lapo ẹ lo gbe e de’bẹ, o ni iṣẹ adigunjale loun fi n ṣe.

CSP Adekunle Ajiṣebutu, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, lo jẹ k’ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ yii ninu atẹjade to fi sọwọ sori ikanni wa lọjọ Wẹsidee. O ni aago mẹsan-an owurọ ọgbọnjọ, oṣu kọkanla, ọdun yii, lọwọ tẹ afurasi ọdaran naa, lasiko tawọn ọlọpaa to n gbogun ti iwa ọdaran n ṣe patiroolu wọn lagbegbe naa.

Bawọn ọlọpaa naa ṣe n kọja lọna NEPA, ni ọja Alaba Rago to wa lagbegbe Ọjọọ, ni wọn fura si Abdullahi, bi wọn si ṣe pe e lati wadii ẹni to jẹ, dipo ko da wọn lohun, niṣe lo ki ere buruku mọlẹ, to n sa lọ, lawọn naa ba gba fi ya a, wọn si ri i mu.

Nigba ti wọn yẹ ara ẹ, wọn ba ibọn ibilẹ meji, kolo ọta ibọn ti wọn o ti i yin kan to tọju sinu baagi to gbe kọrun. Ni teṣan ọlọpaa lo ti jẹwọ pe iṣẹ adigunjale loun n ṣe, o loun ra awọn ibọn naa ni, oun o ki i ṣe ara ikọ kankan, oun nikan loun maa n da lọọ jale, agbegbe Alaba si Ọjọọ toun n gbe naa loun ti n jale toun.

Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, lo paṣẹ pe ki wọn taari afurasi ọdaran yii si Panti, ibẹ ni yoo si gba dele-ẹjọ ti iwadii ba ti pari, gẹgẹ b’Ajiṣebutu ṣe wi.

Leave a Reply