Esi ibo gomina: Mọlẹbi Adeleke, ẹgbẹ PDP n dawọọ idunnu l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Beeyan ba gẹṣin ninu awọn mọlẹbi ẹni ti ajọ eleto idibo ṣẹṣẹ kede gẹgẹ bii gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ademọla Adeleke, tọhun ko ni i kọsẹ rara. Sinkin ni inu wọn n dun, ti wọn si n kọrin ayọ nitori bi wọn ṣe jawe olubori.

Ninu fidio kan to gba ori ẹrọ ayelujara ni awọn mọlẹbi Adeleke ti kora wọn jọ ninu ile rẹ niluu Edẹ, ti wọn n kọrin, ti wọn n fo fayọ, ti wọn n so mọra wọn, ti wọn si n dupẹ lọwọ Ọlọrun.

Lati ọjọ Abamẹta ni ọmọ ẹgbọn gomina tuntun yii, David Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Davido, ti bẹrẹ si i dawọọ idunnu ni tiẹ.

Ninu fidio kan to gbe jade lo ti n so mọ gomina tuntun to jẹ aburo baba rẹ yii. Lasiko ti wọn n ka ibo naa lọwọ ti wọn ti ri i pe didun ni ọsan yoo so fawọn. Bo ti n so mọ Ademọla, bẹẹ lo n so mọ gomina Bayelsa ati olori awọn aṣofin tẹlẹ, Bukọla Saraki, atawọn mi-in ti wọn tun wa nibẹ, ti wọn ti n ki ara wọn ku oriire.

Ọrọ ko fi bẹẹ yatọ ninu ẹgbẹ PDP paapaa, niṣe ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa fọn siigboro laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ti wọn si n fo fayọ, tawọn naa n dawọọ idunnu. Ariwo ti wọn si n pa ni pe ‘imọle ti de, imọle ti wọlu Ọṣun.’’

Ni kutu hai, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni ọga awọn eleto idibo to mojuto idibo ipinlẹ Ọṣun yii, Oluwatoyin Ogundipẹ, kede pe Ademọla Adeleke ti PDP lo jawe olubori nibi ibo Satide naa. Ipinlẹ mẹtadinlogun lo ti yege, nigba ti Gomina Oyetọla to wa nibẹ bayii yege ni ipinlẹ mẹtala.

Leave a Reply