Eto aabo Naijiria daa lasiko yii ju bo ṣe ri ki Buhari too de lọ- Fẹmi Adeṣina

Faith Adebọla

Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, ti gboṣuba fun iṣakoso Muhammadu Buhari lori eto aabo, o ni akitiyan ijọba ti jẹ ki eto aabo sunwọn ju bi nnkan ṣe ri ki wọn too dori aleefa lọ.

Adeṣina sọrọ yii nigba to n dahun ibeere lori eto tẹlifiṣan ileeṣẹ Channels TV, laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. Ijiroro naa da lori atunyẹwo bi iṣakoso to wa lode yii ṣe ṣe si ni idaji saa iṣakoso wọn, paapaa lori awọn koko mẹsan-an ti wọn polongo fawọn eeyan pe awọn fẹẹ mojuto tawọn ba de ori aleefa.

Fẹmi ni: “Bẹẹ ni, a ti mu awọn ileri ta a ṣe fawọn ọmọ Naijiria ṣẹ. Awọn agbegbe kan wa ti a ti kunju oṣuwọn ju ibomi-in lọ o, ṣugbọn tẹnikan ba sọ pe odo la mu delẹdelẹ, irọ ni tọhun n pa.

Lawọn ibi kan, a le ma ṣe daadaa to, ileri mẹta gboogi la ṣe, ileri mẹta naa si pin si ọna mẹsan-an.  Akọkọ ni ti aabo, orileede yii o laabo nigba ta a de. Kia la bẹrẹ iṣẹ lori ẹ, a si dẹkun iṣoro naa, bo tilẹ jẹ pe nigba to tun ya, ọrọ tun bẹyin yọ, o tun burẹkẹ si i, o si di yẹlẹyẹlẹ. Tẹlẹ, iṣoro awọn eeṣin-o-kọ’ku nikan lo n ba wa finra, ṣugbọn ni bayii, ọrọ awọn janduku agbebọn, awọn ajinigbe ati tawọn ẹlẹgbẹ okunkun ti yi wọ ọ. Iṣoro gidi si ni.

Ṣugbọn ta a ba maa sọ ootọ, ṣe a le fi bi eto aabo ṣe ri lọdun 2015 ta a dẹ we bo ṣe ri lasiko yii? Lọdun 2015 yẹn, awọn eeṣin—kọ’ku nikan ni loootọ, ṣugbọn ṣe bi bọmbu ṣe n ro gbau gbau bii ẹni yin banga Keresi kaakiri awọn ilu nla wa lo ṣi n ro lonii? Nnkan ti yatọ, o ti sunwọn si i. Bii igba teeyan fẹẹ ṣabosi ni ti wọn ba n sọ pe eto aabo ko sunwọn rara, o ti sunwọn si i lawọn ibi kan.”

Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina ni ipenija nla ni iṣoro aabo nilẹ wa, erin lakatabu iṣoro ni, ṣugbọn ijọba n ba iṣẹ lọ lori ẹ, iṣẹ gidi si ni pẹlu. O ni ọrọ ẹgan ni bawọn eeyan kan ṣe n sọ pe ijọba yii o kuro loju kan, o ni ijọba to n tẹsiwaju nijọba Buhari.

Leave a Reply