Eto iṣuna ọdun to n bọ yii maa ro awọn araalu lagbara-Ṣeyi Makinde

 Faith Adebọla

Iṣẹ ti de’lẹ fawọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ lati ṣayẹwo aba eto iṣuna owo tijọba ipinlẹ naa maa na feto iṣakoso rẹ lọdun 2022 Gomina Ṣeyi Makinde lo tẹ pẹpẹ aba naa siwaju wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee yii.

Aropọ owo ti iye rẹ din biliọnu meje pere ninu ọọdunrun biliọnu naira (N297 billion) ni Ẹnjinnia Makinde ṣiro pe awọn maa na lọdun to n bọ ọhun.

Nigba to n ṣe ifọsiwẹwẹ bọjẹẹti to pe ni “Bọjẹẹti idagbasoke ati anfaani” naa, Makinde ni aropọ biliọnu mẹrindinlọgọjọ naira (N156,000,136,971) lawọn maa na sori ọrọ-aje ipinlẹ Ọyọ lọdun ta a n sọrọ ẹ yii.

O ni owo tawọn maa naa lori sisan owo-oṣu, ajẹmọnu gbogbo, owo ifẹyinti, awọn ẹtọ ati nnkan eelo fawọn oṣiṣẹ ọba yoo jẹ biliọnu mejidinlogoje aabọ naira (N138,516,308,136).

O sọ pe iṣẹ ode pataki kan tawọn maa nawo le lori lọdun to n bọ ohun ni ọna oni-kilomita aadọfa kan, Ibadan Circular Road, eyi ti awuyewuye ti wa lori ẹ tẹlẹ. O ni ọna naa maa pari, ijọba si maa pawo wọle lori ẹ.

Makinde ni “eyi ni igba akọkọ ti owo ta a maa na sori ipese ohun amayedẹrun ati ọrọ-aje ipinlẹ wa maa pọ ju owo ti a n na fun owo-oṣu ati itọju awọn oṣiṣẹ ọba lọ.

Eto iṣuna yii maa ro awọn araalu lagbara lati le jẹ ki wọn lowo lapo lati ra awọn nnkan to ba wu wọn fun igbe aye idẹrun wọn.”

Leave a Reply