Eto idibo abẹle APC l’Ekoo: Eeyan meji ku, ọpọ fara pa, wọn ji apoti ibo lawọn ibi kan

Faith Adebọla, Eko

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un yii, ni  eto idibo abẹle waye kaakiri awọn agbegbe ijọba ibilẹ ogun (20) ati kansu onidagbasoke marundinlogoji (35) lati yan awọn ti yoo dije dupo alaga ati kansẹlọ ti yoo waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun yii. Alaga ajọ eleto idibo tipinlẹ Eko (LASIEC), Adajọ-fẹyinti Ayọtunde Philips, sọ  l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin, pe kawọn ẹgbẹ oṣelu lọọ bẹrẹ si i gbaradi lati kopa ninu eto idibo ọhun, o ni ipolongo ibo gbọdọ bẹrẹ, ko si pari laarin ọgbọnjọ, oṣu kẹrin, si ọjọ kejilelogun, oṣu keje.

Ikọ akọroyin ALAROYE lọ kaakiri awọn ijọba ibilẹ ati wọọdu ti eto idibo abẹle APC yii ti waye, eyi si lawọn ohun to ṣẹlẹ.

Wọn da eto ibo ru ni Ṣomolu, eeyan meji doloogbe

Ori lo ko oṣiṣẹ ajọ eleto idibo, Ọgbẹni Amida Abudu, ti wọn yan lati mojuto eto idibo abẹle ọhun ni ijọba ibilẹ Surulere yọ, nigba ti awọn janduku kan ṣakọlu si awọn wọọdu ati sẹkiteria ijọba ibilẹ ọhun, ti wọn da eto idibo naa ru, ti wọn ṣakọlu si oṣiṣẹ eleto idibo, ti wọn si tun ji foonu alagbeeka ati baagi rẹ sa lọ.

Eeyan meji ti a ko ti i mọ orukọ wọn la gbọ pe wọn ṣeku pa ninu rogbodiyan to waye naa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan ti wọn sọrọ nipa iṣẹlẹ naa fẹsun kan Olori awọn aṣoju-ṣofin apapọ, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamiala, pe oun lo wa lẹyin iṣẹlẹ aburu ọhun, wọn loun lo lọọ bẹ awọn janduku lọwẹ lati waa da eto idibo naa ru latari bo ṣe jọ pe nnkan o ni i ṣẹnuure fun ondije kan ti wọn loun lo fa a kalẹ.

Ṣaaju, lọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn ọmọ ẹgbẹ APC kan ti fẹhonu han ta ko Fẹmi Gbajabiamila, wọn fẹsun kan an pe niṣe lo fẹẹ fi tipatipa jẹ gaba le awọn ọmọ ẹgbẹ naa lori lagbegbe ọhun, wọn lo ni dandan ni ki awọn eeyan toun fa kalẹ wọle, o si sọ fawọn ti wọn gba fọọmu lati dije tẹlẹ pe ki wọn yọwọ ninu erongba wọn, wọn lo sọ pe oun yoo da owo fọọmu wọn pada fun wọn.

Awọn oluwọde yii ni wọn kegbajare si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Eko lati ba wọn kilọ fun Gbajabiamila, pe ko ma lo ọwọ agbara le awọn lori.

Ohun ta a gbọ ni pe yatọ si Fẹmi Gbajabiamila, awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan tun fẹsun kan alaga ijọba ibilẹ Somolu to wa lori oye lasiko yii, Ọnarebu Ahmed Apatira, wọn loun lo wa nidii iṣẹlẹ ọhun. Wọn lọkunrin naa fẹẹ dije fun saa keji nipo ọhun, ṣugbọn awọn araalu ko gba tiẹ, o si foju han pe yoo fidi-rẹmi, idi eyi lo fi da eto idibo naa ru.

Ṣugbọn alaga naa ti ba awọn oniroyin sọrọ, o loun ko mọ nnkan kan nipa iṣẹlẹ yii, o ni awọn alatilẹyin oun gan-an lawọn janduku naa doju sọ, wọn si ṣe pupọ ninu wọn leṣe gidi. O lawọn ti wọn fẹẹ fi tipa ja ipo gba mọ oun lọwọ lo ṣiṣẹkiṣẹ naa.

Ni Itirẹ-Ikate, wọn ṣe oṣiṣẹ eleto idibo leṣe

Titi di asiko yii ni Ọgbẹni Lateef Ibirọgba ṣi n gba itọju nileewosan aladaani kan n’Ikẹja, latari bawọn janduku ṣe ṣakọlu si i nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ APC ti kansu onidagbasoke Itirẹ-Ikate, ti wọn si da eto idibo naa ru, wọn fọ apoti ibo, wọn si ba awọn aga ati tabili to wa nibẹ jẹ.

Ẹni ori yọ, o di’le lọrọ da lawọn ijọba ibilẹ wọnyi nigba tawọn janduku agbebọn naa ya bo ibi ti wọn ti n ṣeto idibo ọhun, niṣe ni kaluku ba ẹsẹ rẹ sọrọ, pẹlu bi iro ibọn ṣe n ro ni koṣẹkoṣẹ.

“Mo ri awọn gende mẹrin kan, aake to n kọ yanranyanran lo wa lọwọ wọn, wọn tun so ibọn mọ eti ṣokoto wọn, wọn fi aṣọ dudu bo oju wọn. Koda awọn agbofinro to wa nikalẹ sa asala fẹmii wọn pẹlu, onikalulu lo fere ge e.” Ọkan lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ lo sọrọ yii.

A gbọ pe wọn ṣe ọkan lara awọn amugbalẹgbẹẹ alaga kansu Itirẹ-Ikate, Ọgbẹni Ajemọniya, leṣe gidi, wọn lọsibitu lo wa bayii.

L’Alimọsho, agba ẹgbẹ kan fi janduku da eto idibo ru

Nijọba ibilẹ Alimọṣọ, wọn fẹsun kan agba ẹgbẹ APC kan, pe oun lo haaya awọn janduku ti wọn lọọ da eto idibo abẹle naa ru nijọba ibilẹ ọhun. Wọn ni eto idibo naa ti kọkọ bẹrẹ wọọrọwọ, ti nnkan si n lọ letoleto, ṣugbọn bo ṣe ku diẹ ki wọn bẹrẹ si i ka ibo ni wahala de, awọn janduku kan ya bo wọn pẹlu awọn nnkan ija bii ada, aake ati ibọn, wọn si doju apoti ibo de, wọn le awọn eeyan kuro.

Ni Ikosi, eto idibo lọ daadaa lawọn ibi kan, o dojuru lawọn ibomi-in

Lawọn wọọdu kan nijọba ibilẹ onidagbasoke Ikosi-Isheri, lagbegbe Ketu, wọọrọwọ leto idibo naa lọ, nigba ti ẹkọ ko ṣoju mimu rara lawọn wọọdu mi-in.

Ọgbẹni Ahmed Akeem, alaga APC Ward G, o ni wọn o jẹ kawọn eeyan dibo, o fẹsun kan alaga kansu naa, Ọmọọba-binrin Bada pe niṣe lo fi awọn ọmọọta se awọn eeyan mẹyin, ko si jẹ kawọn le dibo, yatọ si oun atawọn to jẹ tiẹ nikan lo wa lori ila ti wọn n dibo lọ. O tun ni ija ti ṣẹlẹ ni Wọọdu ọhun laaarọ ọjọ naa, o ni wọn fọgi mọ ondije fun ipo kansẹlọ kan lori, wọn si ṣe oun alara leṣe.

Ṣugbọn akiyesi ti ALAROYE ṣe ni wọọdu naa ni pe eto idibo n lọ wọọrọwọ, awọn eeyan wa lori ila, wọn si n lo iwe jijẹ ọmọ ẹgbẹ APC lati dibo, bo tilẹ jẹ pe wọn ni akọsilẹ awọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ ti wọn fi ṣọwọ lati ile ẹgbẹ naa ko pe, eyi lo mu ki wọn lo iwe jijẹ ọmọ ẹgbẹ fun idanimọ ati ẹtọ lati dibo

A ba Alaga kansu naa, Simiat Bada, sọrọ, o ni ko si ootọ kan ninu ẹsun ti wọn fi kan oun, o ni wọọrọwọ ni eto idibo naa n lọ, awọn ti wọn fẹsun kan oun ko le mu ẹri kan jade, ko si si iṣẹlẹ aburu kan to ṣẹlẹ ni wọọdu oun. O ni ẹru lo n ba wọn pe wọn le fidi-rẹmi, eyi lo mu ki wọn maa wa oriṣiiriṣii ẹsun arumọjẹ. O loun nigbagbọ pe lagbara Ọlọrun, didun lọsan maa so foun atawọn ondije to wa pẹlu oun.

Lawọn wọọdu mi-in ta a de, eto idibo ko le tẹsiwaju rara. A gbọ pe wọn ti fija pẹẹta ni Wọọdu B, ati ni wọọdu to wa ni ibudokọ Sẹlẹ, eyi to mu ki wọn da eto idibo abẹle naa duro.

Ni kansu Onigbongbo, Apapa-Iganmu, Badagry, Amuwo-Ọdọfin, Ifakọ/Ijaye, wọn ni wọọrọwọ ni eto idibo abẹle wọn lọ. Ero rẹpẹtẹ to lu jade ni Badagry lati kopa ninu eto idibo ọhun, bẹẹ lọrọ si ri ni Ifakọ/Ijaye pẹlu.

Ṣugbọn ni Onigbongbo, iwọnba awọn eeyan diẹ lo jade. Iwadii wa fihan pe awọn agbaagba ẹgbẹ naa ti paṣẹ latoke pe kawọn to fẹẹ dije lati di ọmooye ṣi ni suuru na, ki wọn fawọn ti wọn wa nibẹ ti wọn ti lo saa kan kọja lati lo saa keji wọn. Bẹẹ la ri awọn alaga ati kansẹlọ ti wọn n ṣe faaji ati koriya fawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu wọn.

Leave a Reply