Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọwọ ajọ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, nipinlẹ Kwara, ti tẹ afurasi meji kan; Abdulrasheed Yinka ati Olowononi Busayọ. Ẹsun fifọ ile onile ati jiji foonu onitọhun lọna Egbejila, lagbegbe Asa Dam, niluu Ilọrin, ni wọn fi kan wọn.
Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Yinka, Busayọ si jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun.
Ọga agba ajọ NSCDC ẹka tipinlẹ Kwara, Makinde Iskil Ayinla, ṣalaye pe Bioku Hussain lo fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ awọn leti ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, pe awọn adigunjale fọ ile oun, wọn si ko foonu oriṣiiriṣii marun-un; Samsung, Nokia ati iPhone lọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ogoji naira ninu mọto rẹ.
Ayinla ni iwadi fi han pe Abdulrasheed Yinka lo lọọ fọ ile Bioku lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta, ọdun 2021, laarin oru, to si ji awọn ẹru naa ko.
O ni lẹyin to ri awọn foonu naa ko lo ta wọn lọpọ fun Olowononi Busayọ to n gbe l’Ojule kẹta, lọna Asa Dam, niluu Ilọrin lẹgbẹrun marun-un naira.
Ọga NSCDC tẹsiwaju pe iwadii awọn fi han pe awọn mejeeji jọ n ṣiṣẹ papọ ni, ati pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti wọn ti n lọwọ ninu iwa ọdaran bii eleyii. Bi Yinka ba ti ji i gbe, Busayọ lo n gba a.
O ni awọn yoo fi wọn jofin nipa gbigbe wọn lọ sile-ẹjọ. O fi da araalu loju pe ileeṣẹ awọn yoo tẹsiwaju ninu ojuṣe rẹ lati gbogun ti iwa ọdaran ati didaabo bo ẹmi ati dukia araalu.