Ẹwọn n run nimu Saheed o, agbẹjọro lo lu ni jibiti l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin kan, Fakẹyẹ Saheed, ti foju bale-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lori ẹsun pe o lu ọlọpaa kan, Popoọla Samuel Oluranti, ni jibiti miliọnu meji aabọ naira.

Agbefọba, ASP Fagboyinbo Abiọdun sọ ni kootu pe inu oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ni olujẹjọ huwa naa lagbegbe Atinukẹ Ọyawọye, Dada Estate, niluu Oṣogbo.

Fagboyinbo sọ siwaju pe ṣe ni olujẹjọ parọ gba owo naa lọwọ olupẹjọ pẹlu ileri pe oun yoo san an pada ni gbedeke asiko ti wọn jọ ṣadehun, to si fun un ni ayederu ṣẹẹki ileefowopamọ Access.

Ṣugbọn nigba ti asiko to ni olujẹjọ sa lọ, ti ko si si ẹnikankan to gburoo rẹ mọ, to si jẹ pe lẹyin ọpọlọpọ wahala ni ọwọ too tẹ ẹ.

Fagboyinbo ni iwa ti olujẹjọ hu ọhun nijiya labẹ ipin okoolenirinwo o le ẹyọ kan ati ojilenirinwo o din mọkanla abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Nigba ti wọn ka awọn ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ si i leti, o ni oun ko jẹbi rara.

Lẹyin eyi ni Onidaajọ O.A Daramọla fun un ni beeli pẹlu miliọnu kan naira ati oniduuro meji ni iye kan naa, o si sun igbẹjọ di ọjọ kejidinlogun, oṣu kin in- ni, ọdun 2022.

Leave a Reply