Ẹwọn oṣu mẹrin pẹlu iṣẹ aṣekara ladajọ ju obinrin to faṣọ oṣiṣẹ KAI ya l’Ekoo si

wn ou mrin plu iṣẹ aekara ladaj ju obinrin to faṣọ oṣiṣẹ KAI ya l’Ekoo si

Adewale Adeoye

Wọn ni ko si awijare kankan fẹni to faṣọ ọlọpaa gba paarọ, bẹẹ gan-an lo ri fun omidan kan ti wọn fẹsun kan pe o faṣọ ya mọ oṣiṣẹ ‘Kick Against Indicipline’ (KAI) kan lọrun pẹrẹpẹrẹ niluu Eko lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe ọsẹ yii lawọn oṣiṣẹ ajọ ọhun lọ kaakiri aarin ilu Eko lati fọwọ ofin mu awọn kan ti wọn tapa sofin irinna nipa pe wọn ko ṣamulo biriiji ẹlẹsẹ tijọba Eko ṣe fun awọn araalu, gbogbo awọn araalu ti wọn ba sọda titi lawọn oṣiṣẹ ajọ Kai ọhun n fọwọ ofin mu ju sinu mọto wọn lati gbe wọn lọ si kootu, ṣugbọn nigba ti wọn fọwọ ofin mu omidan kan lagbegbe Ile-Epo, niṣe lo doju ija kọ awọn oṣiṣẹ ajọ ọhun, to si faṣọ ya mọ wọn lọrun lọjo naa. Pẹlu gbogbo agidi ti ọmọbinrin naa ṣe, wọn fọwọ ofin mu un, wọn si foju rẹ bale-ẹjọ lori ohun to ṣe yii. Adajọ kootu ti wọn foju rẹ ba sọ ọ sẹwọn oṣu mẹrin pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn.

Kọmiṣanna fun eto ayika nipinlẹ Eko, Ọnarẹbu Tokunbọ Wahaab, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ Keji, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn araalu mẹrindinlaaadọta ni ajọ Kai fọwọ ofin mu lori iwa ibajẹ pe wọn ko lo biriiji ẹlẹsẹ lati sọda titi lawọn agbegbe bii Oṣodi-Oke ati Ile Epo, ti wọn si ti foju wọn bale-ẹjọ, ṣugbọn ti omidan kan lo yatọ laarin gbogbo wọn, nitori nigba ti wọn mu un fun ẹsun pe ko lo biriiji ẹlẹsẹ tijọba Eko ṣe fun awọn araalu, o doju ija kọ wọn, o si faṣọ ya mọ wọn lọrun, awọn si foju rẹ bale-ẹjọ, adajọ si ti ju u sẹwọn oṣu mẹrin pẹlu iṣẹ aṣekara, ko le jẹ ẹkọ fun awọn to ba tun fẹẹ ṣe bẹẹ.

Leave a Reply