Igi ti wọn fẹẹ fi dana lawọn ọmọ yii lọọ ji tawọn ajinigbe fi ji ọgbọ̀n gbe ninu wọn

Adewale Adeoye

O kere tan, awọn ọmọde bii ọgbọn ni iroyin ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ajinigbe kan ti ji gbe sa lọ niluu kekere kan ti wọn n pe ni Kasai, nijọba Batsari, nipinlẹ Katsina. Iṣẹlẹ naa waye laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe lojiji lawọn oniṣẹ ibi naa yọ sawọn ọmọ ọhun lasiko ti wọn n wa igi idana ti awọn obi wọn fi maa dana ounjẹ fun wọn, loju-ẹsẹ ti wọn ji wọn gbe ni wọn ti ko wọn wọnu igbo lọ.

Ọkan lara awọn araalu ọhun to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun sọ pe laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn ọmọde naa tiye wọn to ọgbọn n wa igi idana ti awọn obi wọn fi maa dana fun wọn, lojiji ni awọn oniṣẹ ibi naa yọ sawọn ọmọ ọhun, wọn ji wọn gbe sa lọ. A nigbagbọ pe wọn maa gba wọn silẹ laipẹ yii, bẹẹ la gbadura pe ki Ọlọrun Ọba da ifọkanbalẹ pada saarin ilu wa laipẹ.

Gomina ipinlẹ naa ati awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọwọ.

 

Leave a Reply