Awọn agbebọn tun ji akẹkọọ fasiti meji gbe sa lọ  nipinlẹ Taraba

Adewale Adeoye

Meji lara awọn akẹkọọ ileewe giga ‘Federal University’,  to wa lagbegbe Wukari, nipinlẹ Taraba, Joshua Sardauna ati Obianu Elizabeth, ni awọn agbebọn kan ti ji gbe sa lọ bayii. Bẹẹ ni wọn ko ti i pe awọn alaṣẹ ileewe ọhun tabi ijọba ipinlẹ naa lati sọ ohun ti wọn fẹẹ gba lọwọ wọn ko too di pe wọn maa ju wọn silẹ lahaamọ.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni awọn ọdaran ọhun lọọ ji awọn akẹkọọ ọhun gbe nile ijẹun igbalode kan to wa laarin ọgba ileewe naa. Gbara tawọn agbebọn ọhun de sinu ọgba ileewe yii ni wọn ti bẹrẹ si i yinbọn soke gbaugbau lati fi da ipaya sọkan awọn akẹkọọ ileewe naa. O si to wakati kan daadaa ti wọn fi ṣoro bii agbọn ninu ileewe ọhun ko too di pe wọn sa lọ lẹyin ti wọn ji awọn akẹkọọ ọhun gbe tan.

Ọga eleto aabo ninu ọgba ileewe naa, Ọgbẹni Sule Gani, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn akẹkọọ ọhun ti wọn ji gbe jẹ awọn ti wọn pada sinu ọgba ileewe naa lati tun idanwo wọn ṣe ni.

Ṣa o, awọn ọlọpaa agbegbe naa atawọn alaṣẹ ileewe ọhun ti n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu lati gba awọn akẹkọọ ileewe naa silẹ ninu ahaamọ awọn ajinigbe ti wọn ṣiṣẹ laabi naa laipẹ yii

 

Leave a Reply