Eeyan kan dero ọrun nibi ija agba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n’llọrin 

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii, ni ọrọ di bo o lọ o yago lọna, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun fija pẹẹta lagbegbe Ọmọ́dá, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Lasiko naa ni ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ ti pade iku ojiji.

Ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ yii ni wọn ni wahala ọhun bẹrẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n jija agba lagbegbe Ọmọ́dá, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin West, ti wọn n rẹ ara wọn danu bii ila, ti wọn si n rọjo ibọn lakọlakọ. Gbogbo awọn to n gbe agbegbe naa ati awọn to n taja lawọn ṣọọbu jẹẹjẹ wọn ni wọn tilẹkun mọri, tawọn to wa nirona si sa lọ. Bẹẹ ni gbogbo awọn awakọ, to fi mọ awọn ọlọkada, n lọri pada, ti gbogbo opopona si da paro-paro.

Lẹyin ti gbogbo ija naa rọlẹ tan ni wọn ri oku gende-kunrin kan ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ, to jẹ ọkan lara wọn, Wọn ni aake ni wọn fi kun ọmọkunrin naa bii ẹran ewurẹ.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ to ba akọroyin ALAROYE sọrọ sọ pe sadeede lawọn ri awọn gende-kunrin ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti wọn n le ara wọn kaba-kaba, lẹyin eyi ni awọn ri i ti wọn n sa ọmọkunrin kan laaake titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ. Ṣugbọn ko sẹni to le duro wo awọn ẹruuku ọhun lasiko ti wọn n ṣiṣẹ buruku naa lọwọ.

Leave a Reply