Ṣẹyin naa ti gbọ ohun to ṣẹlẹ si Bobrisky lọfiisi awọn EFCC?

Faith Adebọla

Boya ni ọkunrin to ti fẹẹ sọ ara ẹ di obinrin tan, to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta yii, Idris Okunẹyẹ, tawọn eeyan tun mọ si Bobrisky, yoo lalaa lati di ero ahamọ nigba kan, amọ lasiko yii, ki i ṣe pe o dero ahamọ lasan, o ti sun oorun ọjọ kan nibẹ, ko si ti i si ireti pe yoo jade, afaimọ ni ki i ṣe ahamọ naa ni yoo gba sọda si kootu, nibi ti yoo ti bẹrẹ si i kawọ pọnyin lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an lọdọ EFCC, latari bi ko ṣe ṣee ṣe fun un lati kaju beeli ti wọn fun un, o si ti n lo ọjọ meji lọgba ẹwọn ajọ naa.

Ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lawọn ẹṣọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti lilu, ṣiṣẹ owo ilu mọkumọku ati awọn iwa ibajẹ to jẹ mọ ti owo ilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka ti ipinlẹ Eko, lọọ fọwọ ofin mu Bobrisky, wọn loo n na owo Naira bii ẹlẹda, o fabuku kan owo beba ilẹ wa, pẹlu bo ṣe n nawo yẹlẹyẹlẹ loju agbo, to n tẹ owo naa mọlẹ lọ mọlẹ bọ, to si n ṣe owo naa bii beba lasan.

Amọ lọjọ keji ti wọn mu un, iyẹn Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, wọn fun Bobrisky ni beeli, bo tilẹ jẹ pe iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan an ṣi n tẹsiwaju, amọ titi tilẹ ọjọ naa fi ṣu, ko ṣee ṣe lati san beeli rẹ, wọn ni ko kunju oṣuwọn ohun ti wọn n beere fun.

Alukoro EFCC l’Ekoo, Ọgbẹni Dele Oyewale, to sọrọ lori iṣẹlẹ yii lọjọ Tọsidee, ni loootọ ni Bobrisky ṣi wa lakata awọn, ati pe ko ṣee ṣe fun un lati kaju beeli tawọn fun un.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe awọn yoo foju afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ lọjọ Furaidee, ti yoo si bẹrẹ si i kawọ pọnyin rojọ, o lawọn ti pari iṣẹ lori awọn ẹsun ti wọn yoo fi kan an ni kootu.

Oyewale ni: “Aṣa palapala to lodi sofin ti Bobrisky hu nibi ayẹyẹ ikojade fiimu tuntun ti wọn pe akọle rẹ ni ‘Ajakaju’, eyi ti Ẹniọla Ajao ṣẹṣẹ ṣe, ti afihan akọkọ rẹ waye ni gbọngan iworan Film One Circle Mall, lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lo mu ki EFCC ke si Bobrisky lati foju kan wa, ta a si fi pampẹ ọba gbe e.

“Iwadii wa fidi rẹ mulẹ pe eyi ko ni igba akọkọ ti afurasi naa yoo maa huwa abuku si owo Naira, eyi to lodi sofin banki apapọn ilẹ wa.

“Owurọ Ọjọruu, Wẹsidee, lo dero ahamọ wa, amọ a maa foju rẹ bale ẹjọ laipẹ ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ta a tori rẹ mu un.”

Leave a Reply