O ṣẹlẹ! Wọn ni ayederu iwe-ẹri ileewe girama ni gomina Ondo n gbe kiri

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kete ti Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa ti gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bii gomina tuntun ti yoo maa dari eto iṣakoso ipinlẹ Ondo lẹyin iku ọga rẹ, Oloogbe Rotimi Akeredolu, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni ọkan-o-jọkan awuyewuye ti n jẹ yọ lori iwe-ẹri kan to gba lati ile-iwe to ti kẹkọọ jade.

Ohun tawọn alatako gomina ọhun n tẹnu mọ ju lọ ni pe irọ patapata lo wa ninu iwe-ẹri oniwee mẹwaa (Waẹẹki) to ni oun gba ni ileewe girama Ikosi High School, Ketu, eyi to wa nipinlẹ Eko, nibi to ni oun ti kẹkọọ jade lọdun 1982.

Wọn ni ko ṣee ṣe ki wọn da ile-iwe girama naa silẹ lọdun 1980, ki wọn si yara bẹrẹ idanwo Waẹẹki ni 1982.

Ohun ti wọn si n fa lọwọ ree ti lẹta kan fi jade lori ẹrọ ayelujara, ẹnikan to pe ara rẹ ni DCP Tahir Usman lati ọfiisi awọn ọtẹlẹmuyẹ to wa l’Abuja lo fọwọ si lẹta naa, ohun to si pe akọle rẹ ni: Abajade iwadii awọn ọlọpaa lori ẹsun iwe yiyi ati jiji wo ti wọn fi kan Ọgbẹni Lucky Ayedatiwa.

Koko ohun to si wa ninu lẹta ta a n sọrọ rẹ yii ni pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe ìwádìí lori ẹsun ti wọn fi kan Ayedatiwa, ohun ti abajade iwadii ọhun si fidi rẹ mulẹ ni pe, ọdun 1980 ni ijọba Lateef Jakande ti i ṣe Gomina ipinlẹ Eko nigba naa da ile-iwe Ikosi High School silẹ, ti Ayedatiwa ti wọn fẹsun kan si loun ṣe idanwo aṣekagba oniwee mẹwaa nibẹ lọdun 1982, iyẹn lẹyin ọdun meji pere ti wọn ti da a silẹ.

Latigba naa lawọn alatako Ayedatiwa ko ti ri orin mi-in kọ mọ ju pe ayederu iwe-ẹri lo n lo lọ, gbogbo alaye ti awọn amugbalẹgbẹẹ gomina ọhun si n ṣe lati wẹ ọga wọn mọ ko da bii ẹni pe o wọ awọn eeyan wọnyi leti rara, ki agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede ede yii, Ọgbẹni Muyiwa Adẹjọbi, too ṣẹṣẹ waa fi atẹjade mi-in sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin ta a wa yii, ninu eyi ti wọn ti fi abajade iwadii tiwọn naa sita.

Ọdẹjọbi ninu atẹjade rẹ ni irọ ati ayederu patapata ni abọ iwadii ti wọn n gbe kiri lori ẹrọ ayelujara, nitori ko si ẹri idaniloju kankan pe olu ileeṣẹ ọlọpaa l’Abuja ni iwe ọhun ti jade. O ni ti iru nnkan bẹẹ ba tilẹ waye níbikíbi, ẹni to pe ara rẹ ni igbakeji kọmiṣanna ọhun ko laṣẹ labẹ ofin to de awọn ọlọpaa lati gbe iru iwadii bẹẹ jade funra rẹ.

O ni, awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lati mọ hulẹ hulẹ ibi ti atẹjade ọhun ti ṣẹ wa, ti ileeṣẹ ọlọpaa ko si ni i fi ọrọ naa ṣe ọrọ aṣiri rara lẹyin ti awọn ba ti ri okodoro rẹ.

Ọdẹjọbi waa rọ awọn araalu lati kiyesara lori iru iroyin ti wọn yoo maa gbagbọ tabi tan kalẹ.

Leave a Reply