Ẹni Ọlọrun o pa! Inu igbo ti wọn ju ọmọ tuntun yii si ni aja ti fẹnu gbe e wọlu

Monisọla Saka

Ẹni ti Ọlọrun ko pa ko kuku ni i ku lọrọ ọmọ tuntun jojolo kan ti Ọlọrun fi aja kan to n lọ soko ṣe angẹli rẹ nipinlẹ Anambra. Aja yii lo fẹnu gbe e wale lati inu igbo to ti ri i.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ọmọkunrin ti wọn ṣẹṣẹ bi yii ni wọn gbe ju sinu igbo kan niluu Abagana, nijọba ibilẹ Njikoka, nipinlẹ Anambra.

Aja to n fẹnu tulẹ kiri lati le ri nnkan ti yoo jẹ ni ALAROYE gbọ pe o ri ọmọ naa ninu poli baagi ti wọn sọ ọ si.

Oju ọna ti ẹsẹ awọn eeyan ati mọto ki i ti i da si ni ọna naa. Bayii ni aja ọhun fẹnu gbe ọra ti wọn gbe ọmọ ọhun si, to si gbe e jade, lo ba ju u si gbangba ode, kawọn eeyan to n re kọja lọ le ri i, ki wọn si le doola ẹmi ẹ.

Obinrin kan lo pada gbe ọmọ naa to n nu un lara, to si n ṣe itọju ẹ, pẹlu itara ati aroye pe ọdaju ni ẹni to le gbe ọmọ ju si aarin igbo, lai bikita pe ki ẹranko buburu fi i ṣe ounjẹ jẹ.

O ni bawo leeyan ṣe maa gbe oyun fun odidi oṣu mẹsan-an, ti yoo waa pa a ti tabi gbe e ju nu.

Nigba ti wọn n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bo ṣe da ọmọ naa si, wọn ni loootọ iwa ti ko bojumu ni ka maa gbe ọmọ sọnu, amọ dipo ti ẹranko buburu iba fi fa iru ọmọ bẹẹ ya pẹrẹpẹrẹ, ki awọn ọdaju abiyamọ bẹẹ kuku gbe ọmọ naa fẹni ti yoo tọju rẹ daadaa.

Ẹni kan to ba iwe iroyin Nigerian Tribune sọrọ lai darukọ ara ẹ ṣalaye pe alaafia ni ọmọ naa wa, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọgba ti wọn ti ju u sibi to wa.

O ni, “Ninu lailọọnu ni aja ti ba ọmọ ti wọn kọ ti sinu aginju yii. Gẹgẹ bi akiyesi wa, yoo ti to ọjọ meji ti ọmọ yẹn ti wa nibẹ ki aja too gbe e wa si aarin ilu ti wọn ti ri i he”.

Epe lawọn eeyan n ṣẹ fun obinrin to bimọ yii, bi wọn ko tilẹ mọ ọn.

Wọn ni ti ki i baa ṣe pe Ọlọrun ni ẹmi ọmọ naa i lo, tabi pe Ọlọrun fọwọ tọ aja naa lọkan ni, ninu igbo nibẹ ni ọmọ to waye ẹ jẹẹjẹ yii iba ṣegbe si.

Wọn waa ṣe e laduura fawọn ti wọn gbe ọmọ naa pe Ọlọrun yoo ba wọn wo o, yoo bukun fun wọn, yoo si pese fun wọn lati tọju rẹ daadaa.

Leave a Reply