Iwakusa lọna aitọ yoo dopin tijọba apapọ ba n ṣewadii awọn ileeṣẹ ti wọn n fun ni lansẹnsi – Fakẹyẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Ọṣun lori ọrọ iwakusa, SP Olumuyiwa Fakẹyẹ, ti ke si ijọba apapọ lati dẹkun lilo oṣelu tabi isunmọni lati fun awọn ileeṣẹ iwakusa ni lansẹnsi.

O ni bi ọrọ lansẹnsi iwakusa ṣe di iru wa, ogiri wa lorileede yii lo n fa a ti ko fi si amotoju to peye latọdọ ijọba apapọ, ti awọn ileeṣẹ naa si n ṣe bo ṣe wu wọn lagbegbe ti wọn wa.

Fakẹyẹ, ẹni to sọrọ yii fun ALAROYE nibi ayẹyẹ ifẹyinti rẹ lẹyin to lo ọdun marundinlogoji lẹnu iṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe ijọba apapọ gbọdọ gbe igbimọ amuṣẹya kan kalẹ lati maa ṣamojuto iṣẹ awọn awakusa ti wọn n fun ni lansẹnsi.

O ni ti ẹka kan ba wa labẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ iwakusa lorileede yii to n ṣayẹwo finnifinni nipa ipilẹ, iriri ati irinṣẹ ileeṣẹ ti wọn ba fẹẹ fun ni iwe aṣẹ, yoo jẹ ijanu fun awọn ileeṣẹ naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’Ijọba apapọ gbọdọ ni ikọ amuṣẹya kan tabi ẹka kan labẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ iwakusa. Wọn ko gbọdọ maa lo ọrọ oṣelu tabi isunmọni lati fun ẹnikẹni niniwee aṣẹ.

‘’Bakan naa ni awọn ijọba ipinlẹ ni lati kọkọ ro ipa ti iwakusa yoo ni lori agbegbe ti awọn ileeṣẹ iwakusa ba fẹẹ duro si, eleyii ni yoo jẹ ki wọn le fun awọn ileeṣẹ yẹn ni alakalẹ awọn nnkan ti wọn gbọdọ ṣe fun iru agbegbe bẹẹ.

‘’Eyi ti wọn ba mọ pe o le ṣakoba pupọ fun ilu, wọn ko gbọdọ faaye gba a. Ijọba gbọdọ ṣayẹwo finnifinni si iṣẹ atawọn irinṣẹ ko too di pe wọn yoo fun ileeṣẹ kankan laṣẹ lati lọọ maa wa kusa nibikibi’’

Nipinlẹ Ọṣun, Fakẹyẹ, ẹni to ṣiṣẹ gbẹyin gẹgẹ bii DPO ọlọpaa niluu Ìperindó, sọ pe ibaṣepọ to wa laarin ọfiisi oun gẹgẹ bii oludamọran fun gomina lori ọrọ iwakusa ati ikọ amuṣeya JTF tijọba gbe kalẹ jẹ ko rọrun lati le kapa awọn ayederu awakusa.

O ni akoba nla ni awọn ayederu awakusa n ṣe fun agbegbe ti wọn ba wa, idi niyẹn tijọba ipinlẹ Ọṣun ko ṣe fi ọwọ kekere mu ọrọ wọn, ti wọn ko si foju wọn balẹ rara.

Leave a Reply