Aṣiri tu! Ọwọ tẹ ayederu EFCC, ọpọ araalu lo ti lu ni jibiti n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ wa, ‘Economic And Financial Crimes Commision’ (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, ni afurasi kan, Akọgun Rasheed Usman, wa bayii. Ẹsun lilu awọn araalu ni jibiti pẹlu ileri pe oun yoo ba wọn gba beeli awọn ọmọ Yahoo meji to wa lahaamọ EFCC, to si n pe ara rẹ ni ojulowo oṣiṣẹ EFCC ni wọn tori ẹ mu un. Iwa to hu yii ni wọn lo ta ko iwe ofin ilẹ wa.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni ọwọ EFCC tẹ Usman, lori ẹsun jibiti lilu ti wọn fi kan an ọhun.

ALAROYE gbọ pe ọmọkunrin to n gbe niluu Babanla, nijọba ibilẹ Ìfẹ́lódùn, nipinlẹ Kwara, yii lo n pe ara rẹ ni ojulowo EFCC, to si gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (500,000), lọwọ obinrin kan, Khadizah Abdul,

gẹgẹ bii owo ti yoo fi gba beeli awọn ọmọ iya naa meji to wa lakata ajọ ọhun, eyi ti wọn fẹsun lilu jibiti lori ayelujara kan silẹ, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ bayii.

Ṣugbọn lẹyin ti Usman gbowo naa tan lọwọ iya wọn ni ko ri awọn ọmọ naa tu silẹ, to si tun n beere fun ẹgbẹrun lọna igba Naira gẹgẹ bii afikun owo to ti gba tẹlẹ lọwọ Khadizah, lẹyin-o-rẹyin ni aṣiri ọrọ naa pada tu pe ayederu EFCC ni. Ileewosan Jẹnẹra ilu Ilọrin, to wa lagbegbe Taiwo-Òkè, ni ọwọ ti tẹ ẹ.

Bakan naa ni wọn lo tun n parọ pe oṣiṣẹ ile-ẹkọ olukọni agba niluu Òró, nipinlẹ Kwara, Kwara State College of Education), loun.

Ajọ naa ni lẹyin tawọn ba pari ẹkunrẹrẹ iwadii lawọn yoo foju Usman ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply